SS 1 YORUBA LANGUAGE .

10/09/2020

Atunse si ibeere ise ose kerindinlogun


1 ọ̀rọ̀ àyálò àfétíyá
tébù
tíṣà.
bọ́tà
télọ̀
pẹ́nṣù
ráìsì
Ọ̀rọ̀ àyálò àfojúyá
Pétérù
Párádísè
Díákónì
Ẹsítérì

2.fork = fọ́ọ̀kì/fọ́ọ̀kù
tailor – télọ̀
brick – bíríkì
globe – gílóòbù
ink. – yín-ìnkì
razor – réṣọ̀
driver – dírẹ́bà/dírẹ́fà/dẹ́rẹ́bà
hospital – ọsibítù/ọsipítū
minister – mínísítà
messenger – mẹ́séńjà

Ise ose ketadinlogun

  1. Asa ti a fi n mo ise ti omo yoo se ni _(a)akosejaye. (b) ikomojade (d)ifa dida (e) iwure
  2. Ise akoko ti awon baba nla wa koko se ni ise __.(a)aso hihun (b) ila kiko (d)ilu lilu (e) agbe
  3. Aboruboye ooo ni a ki_____. (a)alaro (b)aborisa (d)ode (e)babalawo
  4. Ise ona ni __.(a)aso hihun (b)epo fifo (d) ode sise (e) odo gbigbe
  5. Emu je ara ohun elo ise _. (a)alagbede (b)ode (d)gbenagbena (e)ahunso
  6. Biribiri je ara ohun elo ise __.(a) ahunso (b)alagbede (d)ode (e)agbe
  7. Alaro ni a n ki ni __. (a) arepa o. (b) aredu o (d)aroye o (e) arinpa o
  8. Ewo ni o jemo oge sise okunrin? (a) eyin pipa (b) irun Didi (d)laali lile (e) ori fifa
  9. Aso imurode okunrin ni____. (a)iteko (b)dangodo (d) tobi (e)aran
  10. Aso ise fun okunrin ni____. (a)gberi ode (b) dansiki (d)kafutaani (e)kijipa
  11. Orisii sokoto okunrin ni _.(a)abidan (b)kijipa (e)sulia
  12. Okiribi,adiro,ikori ati onide je apeere __(a)fila (b)sokoto (d)buba (e) irun Didi
  13. Awon wo ni o n ko ila oju? (a) alagbede (b)oloola. (d) gbenagbena. (e) onise ona.
  14. ila ooro kookan ni ereke ni ila awin . (a) Egba (b) Ijebu. (d)Ondo (e)Oyo 19.Apeere ila oju kiko ni yii ayafi. (a) keke (b)gombo (d)abaja (e)ikori
  15. Ewo ni ki I se ere osupa ninu ere idaraya wonyii? (a) bojuboju (b)ekun meran (d) bookobooko (e)eke

03/09/2020

Atunse si ibeere ise ose keedogun

  1. Yatọ sí ìyàwó àti ọmọ Ọládẹ̀jọ,awon osise meta lo wa níle won. Alabi, Bayo ati Oyeladun.
  2. Oyeladun lo se Ise omodo
  3. Awon eda inu itan ni :Adio, Abeni, Baba Adio, Oloye Oladejo, Adija, Oyeladun, Bosipo, Adu, Alabi, Bayo.
  4. Adio lo mu okele eba dani to o n reti obe
  5. Abeni ni Dokita ti o wa se itoju oun ni Oladejo
  6. Baba Adio ni o mura bi eegun
  7. Adio gbo pe oga re fe da a duro lenu ise lai mo idi re eyi lo fi sare lo si ile awon oga re lati lo mo idi abajo.
  8. Oyeladun ko le lo si ile eko nitori pe awon obi re ko ri owo lati ran an lo.
  9. Oyèládùn bá Bosipo ṣe iṣẹ́ ìṣirò?
  10. Ẹ̀ṣẹ̀ ti Ọládẹ̀jọ ní Àdìó se ni jiji eru oun ko, o si tun ro ejo oun fun awon onibode

Ise ose kerindinlogun

Deeti: 03/09/2020

Akori : ORO AYALO


Ọ̀rọ̀ ayálò ni àwọn ọ̀rọ̀ èdè mìíràn tí a yá wọ inú èdè Yorùbá. Yorùbá máa ń yá èdè Gẹ̀ẹ́sì, Hébérù, Lárúbáwá àti Hausa. Àpẹẹrẹ: tábìlì, àlàáfíà, Pétérù abbl.

Ọ̀nà tí àwọn ọ̀rọ̀ ayálò gbà wọ inú èdè Yorùbá ni nipasẹ ẹ̀sìn, òwò/ètò ọ̀rọ̀-ajé, òṣèlú, àṣà àti ọ̀làjú.
Bí àpẹẹrẹ mọ́ṣáláṣí,Díákónì, mílíọ̀nù,mílíìkì, Gómìnà abbl.

Yorùbá ní ìlànà méjì tí wọn ń gbà yá ọ̀rọ̀ wo inú èdè. Èyí ni:

  1. Ìlànà àfétíyá : èyí ni pípé àwọn ọ̀rọ̀ ayálò ní ọ̀nà tó súnmọ́ bí elédè ṣe pè é. Bí àpẹẹrẹ Bible – Báíbù, table- tébù.
    2.ìlànà àfojúyá : èyí súnmọ́ ìlànà bí àwọn elédè ṣe ń kọ lẹ́tà ọ̀rọ̀ sílẹ̀. Àpẹẹrẹ.table-tábílì, Bible – Bíbélì.

Ìlànà fonọ́lọ́jì tí a fí ń yá èdè níwọ̀n yìí:
(i) níbi tí kọnsónáńtì méjì bá ti jẹyọ tèléra ,fáwẹlì ‘u’ tàbí ‘i’ a jẹyọ láàárín wọn.
Àpẹẹrẹ bread – búrẹ́dì, glass -gíláàsì,.
(ii) kọnsónáńtì kì í parí ọ̀rọ̀ Yorùbá, a lè fi fáwẹ̀lí ‘u’ tabi ‘i’ tàbí kí á gé e kúrú.
Àpẹẹrẹ gum- gọ́ọ̀mù , fail- féèlì, lantern- láńtà, mobil – móbì.


Iṣẹ́ ṣíṣe

  1. Pín àwọn ọ̀rọ̀ ayálò yìí sí àfétíyá àti àfojúyá : tébù, Pétérù, tíṣà, bọ́tà, Díákónì, ráìsì, télọ̀, párádísè, pẹ́nsù, Ẹsítérì.
  2. Kọ bí a ṣe lè yá àwon ọ̀rọ̀ gẹ̀ẹ́sì yìí wọ inú èdè Yorùbá : fork, tailor, brick, globe, ink, razor,driver, hospital,minister, messenger.

27/08/2020
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹẹ̀dógún
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá

  1. Dárúkọ bátánì/ ìhun Sílébù tí ó wà.
    (a) fáwẹ̀lì nìkan /F/
    (b) àpapọ kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ̀lì /FK/
    (d)kọ́ńsónáǹtì aránmú asesílébù /N/

2.Kọ ìró kọọkan fún àfipè yìí : afèjìètèpè, : b ,m
aréhọ́n,: r
afàfàséfètèpè,: p,gb,w
aṣẹ́nupè,: t, b, d, k, g
àhanudíẹ̀pẹ̀: e, o
afàjàpè, : y
akùnyùn: b, t,d,m,n, g,gb…..

Pín àwọn ọ̀rọ̀ yìí sí Mọ́fíìmù:
Ìdárò : ì/dá/arò
Ilégbèé: ilé/ ì/ gbé
Ọ̀mùtí: ọ̀/ mú/ ọtí
àìlówólọ́wọ́ : àì/ní/owó/ní/ ọwọ́
Ọmọdekunrin : ọmọdé/ ọkùnrin
akọ̀pẹ : a/ kọ/ ọ̀pẹ
Ìdílé : ìdí/ ilé
Òǹtajà: òǹ/ ta/ ọjà
ẹranko: ẹran/ oko
aláǹtakùn : aláǹtakùn

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹẹ̀dógún
Déètì: 27/08/2020
Àkòrí: Lítíréṣọ̀ Àpilẹ̀kọ
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí láti inú ìwé kíkà Nítorí Owó

  1. Yatọ sí ìyàwó àti ọmọ Ọládẹ̀jọ, ọ̀ṣìṣẹ́ mélòó ló wà nílé Ọládẹ̀jọ? Dárúkọ wọn
  2. Iṣẹ́ kín ní Oyèládùn lọ ṣe ní ilé àwọn Bọ̀sípọ̀?
  3. Dárúkọ ẹdá ìtàn márùn tó wà nínú ìwé yìí
  4. Ta ni ó mú òkèlè ẹbà dání tó ń retí ọbẹ̀?
  5. Ta ni Àbẹ̀ní pe Ọládẹ̀jọ nígbà tí Bàbá Àdìó bá wọn pé nínú ilé?
  6. Ta ni eégún?
  7. Kín ní ó sáré gbé Àdìó lọ sílé ọga rẹ̀ Ọládẹ̀jọ, lọ́jọ́ tó ti ìrìn àjò dé?
  8. Nítorí kín ni Oyèládùn kò ṣe lọ sí ilé ẹ̀kọ́?
  9. Ta ni Oyèládùn bá ṣe iṣẹ́ ìṣirò?
  10. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Ọládẹ̀jọ ní Àdìó ṣẹ òun tí ó fi fẹ́ dá a dúró?

20/08/2020

ISE OSE KERINLA

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹtàlá
Ṣe àtúnkọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní àkọtọ́ òde òní

  1. aiya : aya
  2. ẹiyẹ : ẹyẹ
  3. enia : ènìyàn
  4. Ọn : òun
  5. Sun u : sun ún
  6. Pọn o : pọn ọ́n
  7. Nwọn : wọn
  8. Ẹ̀nyin : ẹ̀yin
  9. Ọffa : ọfà
  10. Oṣhogbo : òṣogbo
  11. Ṣhàgámù : ṣàgámù
  12. Õrùn : òòrùn
  13. kíni: kìíní
  14. Ọkọrin : ọkùnrin
  15. Obirin : obìnrin
  16. Nlọ : ń lọ
  17. Wípé : wí pé
  18. gẹgẹbi : gẹ́gẹ́ bí
  19. Nitorina : nítorí náà
  20. Nitoriti : nítorí tí
  21. Níwọ̀nìgbàtí : níwòn ìgbà tí
  22. Bíótilẹ̀jẹ́pé : bí ó tilẹ̀ je pé
  23. Mẹ́tta : mẹ́ta
  24. Tani : ta ni
  25. Yíò : yóò

Déètì: 20/08/2020
Àkòrí: ìbéèrè lórí Ètò Ìró

  1. Dárúkọ bátánì/ ìhun Sílébù tí ó wà.
  2. Kọ ìró kọọkan fún àfipè yìí : afèjìètèpè, aréhọ́n, afàfàséfètèpè, aṣẹ́nupè, àhanudíẹ̀pẹ̀, afàjàpè, akùnyùn
  3. Pín àwọn ọ̀rọ̀ yìí sí Mọ́fíìmù:
    Ìdárò
    Ilégbèé
    Ọ̀mùtí
    àìlówólọ́wọ́
    Ọmọdekunrin
    akọ̀pẹ
    Ìdílé
    Òǹtajà
    ẹranko
    aláǹtakùn

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kejìlá

Ẹ̀yán

  1. Olú = èyán ajórúkọ
    mi = ẹ̀yán arọ́pọ̀ orúkọ
  2. tí a rí ní ọjà. = ẹ̀yán aláwẹ́ gbólóhùn.
  3. Ọmọdé /méjì= ẹ̀yán ajórúkọ/aṣònkà
  4. gan an = ẹ̀yán aṣàfihàn
    Wọn = ẹ̀yán arọ́pọ̀ orúkọ
  5. funfun = ẹ̀yán aṣàpèjúwe
  6. rere = ẹ̀yán aṣàpèjúwe
  7. pupa = ẹ̀yán aṣàpèjúwe
    rẹ̀ = ẹ̀yán arọ́pò orúkọ
  8. tí mo ṣẹṣẹ kàn= ẹ̀yán aláwẹ́ gbólóhùn . àgbède= ẹ̀yán ajórúkọ
  9. yìí = ẹ̀yán aṣàfihàn
  10. wọnyìí = ẹ̀yán aṣàfihàn

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹtàlá
Déètì:13/08/2020
Àkòrí: Àkọtọ́ òde òní
Ṣe àtúnkọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní àkọtọ́ òde òní

  1. aiya
  2. ẹiyẹ
  3. enia
  4. Ọn
  5. Sun u
  6. Pọn o
  7. Nwọn
  8. Ẹ̀nyin
  9. Ọffa
  10. Oṣhogbo
  11. Ṣhàgámù
  12. Õrùn
  13. kíni
  14. Ọkọrin
  15. Obirin
  16. Nlọ
  17. Wípé
  18. gẹgẹbi
  19. Nitorina
  20. Nitoriti
  21. Níwọ̀nìgbàtí
  22. Bíótilẹ̀jẹ́pé
  23. Mẹ́tta
  24. Tani
  25. Yíò

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kejìlá

06/08/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kọkànlá

  1. Ojú Olú / ara mi.
  2. Àgbò tí a rí ní ọjà / Ṣọlá.
  3. Àwọn ọmọdé méjì / ayò.
  4. Èmí gan an/ ìyá wọn.
  5. Ó/ Adìẹ funfun .
  6. Mo/ ọmọ rere.
  7. Aṣọ pupa / ẹ̀gbọ́n rẹ̀ / ọjà.
  8. Àga tí mo ṣẹṣẹ kàn / bàbá àgbẹ̀dẹ.
  9. Won / ọ̀rọ̀ yìí.
  10. Ẹ̀yin wọ̀nyí

Isé ọ̀sẹ̀ Kejìlá

Déètì :06/08/2020

Àkòrí: Ẹ̀yán

Tọ́ka sí àwọn èyán inú gbólóhùn wọ̀nyí kí ó sì sọ irú èyán tí ó je.

  1. Ojú Olú wà ní ara mi.
  2. Àgbò tí a rí ní ọjà wù Ṣọlá.
  3. Àwọn ọmọdé méjì ń ta ayò.
  4. Èmí gan an wa lodo ìyá wọn.
  5. Ó ti pa Adìẹ funfun .
  6. Mo jẹ́ ọmọ rere.
  7. Aṣọ pupa ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rí rà ní ọjà.
  8. Àga tí mo ṣẹṣẹ kàn wà lọ́dọ̀ bàbá àgbẹ̀dẹ.
  9. Wọ́n ti mo sí ọ̀rọ̀ yìí.
  10. Ẹ̀yin wọ̀nyí wà níbẹ̀.

30/07/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹwàá

  1. Pọn= ọ̀rọ̀-ìse aṣàpèjúwe/ aláìgbàgbọ
  2. pa, jẹ = ọ̀rọ̀-ìse oníbọ̀/ẹlélà
  3. Fa, yà =ọ̀rọ̀-ìse oníbọ̀/ẹlélà
  4. gbé, pọn, gùn=ọ̀rọ̀-ìse àsínpọ̀
  5. Jókòó = ọ̀rọ̀-ìse àkànmọ́rúkọ
  6. Kú, kú = ọ̀rọ̀ ìṣe alápèpadà
  7. Jọ̀wọ́= ọ̀rọ̀ ìṣe apàṣẹ
  8. bí = ọ̀rọ- ìṣe asolùwàdàbọ̀
  9. dá = ̀ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè
    10.ga = ọ̀rọ̀ ìṣe aṣàpejuwe

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kọkànlá
Déètì: 30/07/2020
Àkòrí: Àpólà orúkọ
Tọka sí/Fàlà sí ìdí àwọn àpólà-orúkọ inú gbólóhùn wọ̀nyí:

  1. Ojú Olú wà ní ara mi.
  2. Àgbò tí a rí ní ọjà wù Ṣọlá.
  3. Àwọn ọmọdé méjì ń ta ayò.
  4. Èmí gan an wa lodo ìyá wọn.
  5. Ó ti pa Adìẹ funfun .
  6. Mo jẹ́ ọmọ rere.
  7. Aṣọ pupa ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rí rà ní ọjà.
  8. Àga tí mo ṣẹṣẹ kàn wà lọ́dọ̀ bàbá àgbẹ̀dẹ.
  9. Wọ́n ti mo sí ọ̀rọ̀ yìí.
  10. Ẹ̀yin wọ̀nyí wà níbẹ̀.

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹsán
1.arabinrin= ìró/o/ nínú ara obìnrin

  1. yara = ìró/I/ nínú iyara
  2. adie= ìró/y/ nínú adìyẹ
  3. kekee= ìró/r/ ninu kekere
  4. baii= ìró/y/ nínú báyìí
    6.eegun= ìró/g/ nínú egungun
  5. kuo= ìró /r/ nínú kúrò
  6. bante= ìró/I/ nínú ìbànté
  7. busun = ìró/I/ ninu ibusun
    motade= ìró/ọ́/ ninu Ọmọtade

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹwàá
Déètì: 23/07/2020
Àkòrí: Ìtẹ̀síwájú lórí Àpólà ìṣe
Orísìí Ìsọ̀rí ọ̀rọ-̀ìṣe

  1. Ọ̀rọ̀- ìṣe aṣàpèjúwe: irú ọ̀rọ̀ ìṣe yìí ni ó máa tọ́ka sí olùwà.
    Àpẹẹrẹ
    (a) Ọmọbinrin náà kúrú. (Kúrú)
    (b) Iṣu yìí tóbi. (tóbi)
    (d) igi wọn gùn. ( gùn)
    (é) Iṣẹ́ pọ̀. (pọ̀)
  2. Ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè: èyí ni a fi máa ń gbé ìbéèrè kalẹ̀. Méjì péré ni ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè tí ó wà nínú èdè Yorùbá. Àpẹẹrẹ: dà, ńkọ́.
    (a) Àwọn ọmọ ńkọ́? (ńkọ́)
    (b) Aṣọ eégún dà? (dà)
    (d) Ilé yín dà? (dà)
  3. Ọ̀rọ̀- ìṣe apàṣẹ: èyí ni a máa ń saábà lò nínú gbólóhùn àṣẹ nìkan. Àpẹẹrẹ
    (a) Ẹ pẹ̀lẹ́ (pẹ̀lẹ́́)
    (b) Ẹ dákun.(dákun)
    (d) Ẹ kú iṣẹ.́ (kú)
    (e) O káre. (káre)
  4. Ọ̀rọ̀-ìṣe asolùwàdàbọ̀: ọ̀rọ̀ ìṣe asolùwàdàbọ̀ ni èyí tí olùwà àti àbọ̀ le gba ipò ara wọn nínú gbólóhùn. Àpẹẹrẹ:
    (a) Mo bínú. — Inú bí mí.
    (b) Mo jìyà. — Ìyà jẹ mí.
    (d) Ó ṣiwèrè. — Wèrè ṣe é.
    (e) Mo kánjú. — Ojú kán mi.
  5. Ọ̀rọ̀-ìṣe alápèpadà: èyí ni ọ̀rọ̀-ìṣe tí a máa ń ṣe àpètúnpè ọ̀rọ̀-ìṣe kan náà fún nínú gbólóhùn kan. Àpẹẹrẹ:
    (a) Jésù ni a mọ̀ mí mọ̀. (mọ̀)
    (b) Má dá mi dá bùkátà mi. ( dá)
    (d) Ayé kò fẹ́ ní fẹ́ ire. ( fẹ́)
    (e) Kọ́bọ̀ ló kù mí kù. ( kù)
  6. Ọ̀rọ̀-iṣè àkànmọ́rúkọ: èyí ni a ṣá lára àpapọ ọ̀rọ̀ ìṣe àti ọ̀rọ̀ orúkọ. Ó máa ń hàn pé ọ̀rọ̀ orúkọ wà lára ọ̀rọ̀ ìṣe yìí nítorí pé ìṣesí tí ó wà láàárín ọ̀rọ̀ orúkọ àti ẹ̀yán ajórúkọ ni ó máa ń wà láàárín ọ̀rọ̀ ìṣe àkànmọ́rúkọ àti ẹ̀yán ajórúkọ. Àpẹẹrẹ:
    (a) Wọn gbàgbé wa . ( gbàgbé)
    ( b) Bísí pàdée Bọ́lá. (Pàdé)
    ( d) Bàbá náà lawọ́. ( lawọ́)
    (e) Olú ti paná.(paná)
  7. Ọ̀rọ̀-ìṣe aṣokùnfà : èyí ni ó máa ń fa nǹkan tàbí tí ó máa ń mú kí nǹkan ṣẹlẹ̀. Àpẹẹrẹ:
    (a) Ó mú mi ṣe ọ̀gá. (mú)
    (b)Ó dá ẹ̀rín pa mí. (dá)
    (d) Ó kó ìyà jẹ ọmọ náà. (kó)
    (e)Ó fi ìṣe gún mi lẹ́sẹ̀. (fi)
  8. Ọ̀rọ̀ ìṣe oníbọ̀/ ẹlẹ́là: èyí ni ọ̀rọ̀-ìṣe tí a máa ń fi àbọ̀ Pín sí méjì. Àpẹẹrẹ:
    (a) Ọ̀gá àgbà bá ọmọ wí. (báwí)
    (b) Olú ba àga jẹ́. (bàjẹ́)
    (d) Mo tan Títí jẹ. (tànjẹ)
    (e) Adé rẹ́ mi jẹ. ( rẹ́jẹ)
  9. Ọ̀rọ̀ ìṣe àsínpọ̀: èyí ni ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó bá ju kan,méjì, mẹta lọ nínú gbólóhùn. Àpẹẹrẹ:
    (a) Ìyá Ṣọlá ra iṣu ṣè jẹ. (rà,sè,jẹ)
    (b) Wọn ra ẹ̀pà jẹ. ( rà,jẹ)
    (d) Olú kò tètè gbé àga wa.( kò, tètè, gbé , wá)
    (é) ó ti sùn lọ ṣáájú wa. ( Sùn, lọ, ṣáájú)

Àkíyèsí pàtàkì: àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tí ó wà lábé ìsòrí kọọkan ní ó wà nínú àkámọ́()

Isé ṣiṣẹ́
Kọ ọ̀rọ̀ ìṣe inú gbólóhùn ọkan sílẹ, kí ó sì sọ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́

  1. Èso náà pọ́n.
  2. Ìyá pa ẹja jẹ.
  3. Ṣọlá fa ìwé mi ya.
  4. Titi gbé ọmọ pọ̀n gun orí igi.
  5. Ṣọlá jókòó sílẹ.
  6. Ó’ kú alàgbà náà kú kọ́bọ̀.
  7. Ẹ jọ̀wọ́.
  8. Inú bí Òjó.
  9. Ìwọ dà?
  10. Ọmọ náà ga.

Ise ose kesan-an

16/07/2020

Atunse si ibeere ise ose kejo

Iṣẹ́ ṣíṣe
Tọka sí àwọn ìró tí a pajẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí:
(i) àkàà= iro /r/ ninu akara
(ii) èkùọ́́= iro /r/ ninu ekuro
(iii) dáa= iro /r/ ninu dara
(iv) gbárìẹ́= iro /y/ ninu gbariye
(v) gboùngboùn= iro /h/ ninu gbohungbohun
(vi) ọmọlúàbí= iro /w/ ninu omoluwabi
(vii) ralẹ̀ = iro /i/ ninu ra ile
(viii) etídò= iro /o/ ninu eti odo
(ix) dáràn= iro /o/ ninu odaran
(x) fọṣọ = iro /a/ ninu fo aso

Ise ose kesan-an

Deeti : 16/07/2020

Akori: Iparoje

Toka si iro ti a paje ninu awon oro wonyii:

  1. arabinrin
  2. yara
  3. adie
  4. kekee
  5. baii
  6. eegun
  7. kuo
  8. bante
  9. busun
  10. motade

09/07/2020

Atunse si ibeere ise ose keje

  1. Fi ẹnu kọ: ki eniyan si Oro so,ki eniyan soro ti o ju enu re lo
  2. Pàdí àpò pọ : Ni ajosepo lati re elomiran je
  3. Ni ẹyẹ kò sọkà: kiakia,
  4. Òkété bórú:ki nnkan ti eniyan n le ma te e lowo
  5. Fi ọwọ́ lẹ́rán:ki a se suuru, ki a farabale.
  6. ta téru nípàá: ku, di ero orun alakeji
  7. Gbinájẹ: Binu koja aala,faraya
  8. Pa lọ́lọ́: dake roro
  9. Làásìgbo: Oran, wahala,iyonu
  10. ẹ̀pa kò bóró mọ́: ki nnkan ma ni atunse mo

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹjọ
Déètì: 09/07/2020
Àkòrí: Ìpàrójẹ́

Kín ní ìpàrójẹ/ìpajẹ? Ìpajẹ ni fifó àwọn ìró nígbà tí a bá n ṣafọ̀ geere.ìró tí a pajẹ lè jẹ́ ìró kọ́ńsónáǹtì, fáwẹ́lì àti ohùn .

Àpẹẹrẹ Ìpajẹ kọ́ńsónaǹtì b.a
gbárìyẹ̀ – gbárìẹ̀ (y)
Ọ̀mọlúàbí – ọmọlúábí (w)
Kẹ́hìndé – kẹ́ìndé (h)
Èkùrọ́ – èkùọ́ (r)

Àpẹẹrẹ Ìpajẹ fáwẹ̀lì
ra ilé – ralé (i)
etí odò – etídò (o)
ra aṣọ – raṣọ (a)
Ifákúnlé – fákúnlé(I)
Adéjọbí – Déjọbí (A)

Iṣẹ́ ṣíṣe
Tọka sí àwọn ìró tí a pajẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí:
(i) àkàà
(ii) èkùọ́́
(iii) dáa
(iv) gbárìẹ́
(v) gboùngboùn
(vi) ọmọlúàbí
(vii) ralẹ̀
(viii) etídò
(ix) dáràn
(x) fọṣọ

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹfà

  1. Kín ní orúkọ àwọn ìyàwó ṣàngó?
    Ọ̀sun,Ọbà, Ọya
  2. Irú òrìṣà wo ní ọya?
    Òrìṣà tí ń gbé inú afẹ́fẹ́ jà
    3.kin ni orúkọ tí à ń pe àwọn tí wọn wà láti ìdílè egúngún?
    Ọ̀jẹ̀ (Ọ̀jẹ̀rìndé, Ọ̀jẹ̀làdé,Ọ̀jẹ̀níyì, Ọ̀jẹ́yẹmi, Eégúnjobí, Eégúngbèmí, Amúsàn án abbl)
    4.orin àti ìlù tí a ń lù tẹ̀lẹ́ egúngún ni__
    ẹsà egúngún tàbí iwì egúngún

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Keje
Déètì:02/07/2020
Àkòrí: Àkànlò Èdè


Àkànlò Èdè ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ wọn kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan àfi ká wo àkójọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àpapọ láti gbé ìtumọ̀ wọn jáde. Àkànlò èdè máa ń dá lé orí ohunkóhun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ àwa ọmọ ẹ̀dá.
Bí àpẹẹrẹ

Àkànlò ÈdèÌtumọ̀
1. Dójúlékí a máa bá ènìyàn kan ṣoṣo jà
2. tẹ́rí gbaṣọkí ènìyàn kú
3. Fi ikùn lukùnríronú papọ̀ lórí nǹkan
4. Kó ọ̀rọ̀ jẹkí ènìyàn túúbá pé òun kò sọ ohun tí òun wí mọ́.
5.diwọ́ disẹ̀ sínúkí obìnrin lóyún.
6. Fi orí ọká họ imúwá wàhálà tàbí fi ikú ṣeré.
7. Sọ ojú abẹ ní ìkókí ènìyàn sọ ọ̀rọ̀ ní pàtó sí ibi tí ọ̀rọ̀ wà.
8.fi àáké kọ́rí ó kọ̀ jálẹ̀ láti gba ẹ̀bẹ̀.
9. dáwọ́ tẹlẹ̀yàgbẹ́, ṣu
10. rúnpá rúnṣẹ̀kí á sa gbogbo agbára kí nǹkan lè yọrí sí rere.

Iṣẹ́ ṣíṣe

Sọ ìtumọ àwọn Àkànlò èdè yìí:

  1. Fi ẹnu kọ: ki eniyan si Oro so
  2. Pàdí àpò pọ : Ni ajosepo lati re elomiran je
  3. Ni ẹyẹ kò sọkà: kiakia,
  4. Òkété bórú:ki nnkan ti eniyan n le ma te e lowo
  5. Fi ọwọ́ lẹ́rán:ki a se suuru, ki a farabale.
  6. ta téru nípàá: ku, di ero orun alakeji
  7. Gbinájẹ: Binu koja aala,faraya
  8. Pa lọ́lọ́: Fake roro
  9. Làásìgbo: Oran, wahala,iyonu
  10. ẹ̀pa kò bóró mọ́: ki nnkan ma no atunse mo.

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹfà

25/06/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún

  1. Kọ orúkọ merin mìíràn tí Ọ̀rúnmìlà ń jẹ́. Ẹlẹrìí ìpín, Akéréfinúṣọgbọ́n, Amọ̀rànmoyè, Àgbọnmèrègún, Gbáye -g run.
  2. Kín ní èèwọ̀ èṣù? Àdí
  3. Òrìṣà wo ló níṣe pẹ̀lú irin? Ògún
  4. Kọ orúkọ mìíràn tí èṣù ń jẹ́?Láaroyè,Láàlú, Aṣeburúkú-ṣerere,Ògiri òkò
  5. Kín ni pàtàkì Ọ̀rúnmìlà láàárín àwọn Yorùbá? Iṣẹ́ tí Olódùmarè gbé fún un ni láti fi ọgbọ́n to ilé ayé kí ilé ayé lè gún régé.
  6. Kọ mẹ́ta nínú èèwọ̀ ọbàtálá. Ọbàtálá kìí mu omi ìkàsì, kìí mu ẹmu, wúndíá tàbí arúgbó tí kò ṣe nǹkan oṣù mọ́n ló máa ń pọn omi àjípọn sí ojúbo rẹ̀, kọ̀ sì gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ tí yóò fi lọbọ̀, Ọbàtálá kórira èké,àìsòdodo àti ọ̀dalẹ̀.

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹfà
Déètì: 25/06/2020
Àkòrí: Ìtẹ̀sìwájú lórí Àwọn Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá

Ṣàngó
Ọ̀kan pàtàkì ni Ṣàngó Olúkòso jẹ́ láàrin àwọn Òrìṣà Yorùbá.Ṣàngó jẹ́ akọni ènìyàn, jagunjagun tí ó lágbára tí ó sì lóògún. Ìtàn fi yé mi pé ṣàngó ni Aláàfin kẹrin tí ó jẹ ní Ọ̀yọ́ ilé. Ó jẹ́ ọba tí ó lágbára púpọ̀,ó sì ní òògùn tí ó máa ń mú kí iná máa yọ lẹ́nu rẹ̀ bí ó bá ń ṣọ̀rọ̀, ó sì ní òògùn tí ó fi máa ń fi ààrá fa iná sórí ilé àwọn tí ó bá ṣẹ̀ ẹ́. Ìwà ìkà, àìbìkítà, àti apamọlẹ́kún jáyé tí ṣàngó ń jù yìí ló mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ará ìlú dìtẹ̀ mọ́ ọn, tí wọ́n sì rọ ̀lóyè nígbà tí ìnira tí ṣàngó ń fún wọn ti pọ̀ jù fún wọn. Èyí ló mú kí Ṣàngó bínú kúrò ní ìlú tí kò sì rí ẹni tẹ̀lé e àfi ìyàwó rẹ̀ Ọya. Kò pẹ́ tí wọ́n kúrò ní ìlú ní ọya padà lẹ́yìn rẹ̀,èyí ló mú kí Ṣàngó fi ìbínú pokùn so. Ọ̀rọ̀ pé ọba sọ wá di ọ̀rọ̀ ẹ̀fẹ̀ àti tu, èyí sì kó ìtìjú bá àwọn ọ̀rẹ́ Aláàfin Ṣàngó. Èyí ló mú kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wọnyìí lọ kó òògùn tí ṣàngó fi ń fa iná sí ilé ọ̀tá rè, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi ẹdun ààrá faná sórí òrùlé ilé àwọn ọ̀tá ṣàngó tí ó ń sọ pé ọba sọ. Ìbẹrù ṣàngó yìí ló mú kí àwọn ènìyàn yí ohùn padà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé Ọba kò sọ. Ìgbà yìí gan an sì niiiná tó dáwọ́ dúró. Àwọn ìwà líle yìí ló mú kí wọn sọ ọ́ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ.Baba mogbà ní olórí àwọn ẹlẹrìí ṣàngó. Àwọn elégùn ṣàngó máa ń didun, wọn a sì mú iṣé ṣàngó lọ́wọ́. Ìlù bàtá ni wọn lo. Àwọn ohun tí ẹnu ń jẹ bí í orógbó,obì, àgbò ni wọ́n fí ń bọ ṣàngó.

Egúngún
Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá nínú ìgbé ayé mìíràn lẹ́yìn ikú ni ó fa ìdí eégún bíbọ. Wọn gbàgbọ́ pé bàbá àwọn tí ó ti kú kò sùn lọ́run, ó sì lè wá sí ayé gẹgẹ bí ará ọ̀run. Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń pe egúngún ni ará ọ̀run. Ológbojò tàbí Ológbìn-ín ló dá awo egúngún sílẹ̀. Aṣọ tí àwọn egúngún máa ń wọ̀ ni agọ̀ tàbí ẹ̀kú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ni a mọ̀ pé ènìyàn nì ó wà nínú ẹ̀kú iṣẹ́ àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ ni láti máa fi yé àwọn ènìyàn pé ará ọ̀run ni. Ìgbàlẹ̀ ni ilé tí egúngún ti máa jáde wa.Alágbaà ni orúkọ oyè olórí elégùn. Ìlù bàtá ni wọn máa lù tẹ̀lé egúngún pẹ̀lú ẹsà pípẹ́.


Iṣẹ́ ṣíṣe

  1. Kín ní orúkọ àwọn ìyàwó ṣàngó?
  2. Irú òrìṣà wo ní ọya?
    3.kin ni orúkọ tí à ń pe àwọn tí wọn wà láti ìdílè egúngún?
    4.orin àti ìlù tí a ń lù tẹ̀lẹ́ egúngún ni____.

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún

18/06/2020

Ẹ kú u déedé àsìkò yìí ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ mi. Mo rí iṣẹ́ Ìníolúwa,Kányinsọ́lá àti Olúwanífẹ̀mi, mo kí yín kú u iṣẹ́ . Mo ń retí ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ mi tókù.

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹrin

Fàlà sí àpólà ìṣe nínú gbólóhùn yìí.

  1. ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹun.
  1. lọ sí Ìbàdàn.
  2. Wá rí mi.
  3. ga fíofío.
  4. ń ṣiṣẹ́ nítorí ọmọ
  5. máa ń yan bí ológun.
  6. kọ pẹ̀tẹ́sì méje.
  7. jókòó rẹ̀pẹ̀tẹ̀.
  8. ṣubú.
  9. kò gba ìwé náà.

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún
Déètì: 18/06/2020
Àkòrí: Àwọn Òrìṣà Yorùbá


Àwọn òrìṣà ni aṣojú Olódùmarè ní àárín àwọn Yorùbá. Yorùbá gbagbọ́ pé Olódùmarè tóbi ju kí ẹ̀dá máa kọjú sí I béèrè ohunkóhun lọ, ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń gba ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá kọjá láti lè bá wọn gbé ẹ̀bẹ̀ àti àdúrà wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Olódùmarè.

  1. Ọbàtálá/Òrìṣà Ńlá
    Ẹni akọ́dá láti ọwọ́ Olódùmarè ní, òun sì ni igbákejì Olódùmarè tí a fún ní agbára láti ṣe ojú, imú ẹnu etí àti àwọn ẹ̀yà ara yòókù lẹyìn tí Olódùmarè ti dá ara bọrọgidi tán. Ìdí nìyí tí wọ́n fí ń pè é ni Àlámọ rere. Àwọn arọ,abuké,afọ́jú àti àwọn àkàndá mìíràn ni à ń pè ní Ẹni òrìṣà nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn .
    Òrìṣà tí ó fẹ́ràn nǹkan funfun báláú ni Ọbàtálá.Ẹfun ni wọ́n fí ń kún ilé rẹ̀. Aṣọ funfun nì àwọn olùsin rẹ̀ máa ń lò tí won sì máa ń ta sí ojúbọ rẹ̀. Iyán pẹ̀lú ọbẹ̀ ẹ̀gúsí tí a fi òrí sè àti ìgbín ni oúnjẹ rẹ̀. Ọbàtálá kórira ohun ẹ̀gbin àti èérí nítorí náà kìí mu omi ìkàsì(omi ijọ́ Kejì). Àfẹ̀mọ́júmọ́ ní ojoojúmọ́ ni àwọn ìyàwó òrìṣà níláti pọnmi àjípọn sí ojúbọ rẹ̀. Ẹni náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀dọ́mobìnrin tí kò tíì mọ ọkùnrin tàbí arúgbó tí kò ṣe nǹkan oṣù mọ́.Ẹni náà kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀, kò gbọdọ̀ pàdé ẹnikẹ́ni tàbí wẹ̀yìn. Ìdí nìyí tí ẹni náà yóò fi máa mi aaja kí àwọn èèyàn lè yà kúrò lọnà. Ìlù ìgbìn ni won lù níbi ọdún rẹ̀ Ọbàtálá kórira ìwà èké,àìsòdodo, àti ọ̀dàlẹ̀.
  2. Ògún
    Ìtàn kan sọ pé ògún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òrìṣà tí Olódùmarè rán wá sí ilé ayé tí wọn fi ẹ̀wọ̀n rọ̀ wá láti ọ̀run. Ògún nìkan ló mú àdá lọ́wọ́ tí ó fi la ọ̀nà dé ilé ayé. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè é ni Ọsìn ìmọlẹ̀ . Irin àti ohun tí a fi irin ṣe ni àmì ògún Àwọn ọdẹ, jagunjagun, alágbẹ̀dẹ àti àwọn tí ìṣẹlẹ wọn jẹmọ́ irin ni ó máa bọ ògún. Oúnjẹ tí ògún fẹ́ràn ni ajá,ẹ̀sun iṣu,ẹmu. Màrìwò ni aṣọ ògún. Ìjálá sísun ní orin ògún, ìlù agẹ̀rẹ̀, bàtá tàbí dùndún ni ìlù ògún. Ògún kórira ìbúra èké.
  3. Ọ̀rúnmìlà
    Ọ̀rúnmìlà wà lára àwọn òrìṣà tí ó fi ẹ̀wọn rọ̀ wá sáyé. Iṣẹ́ tí Olódùmarè gbé fún un ni láti fi ọgbọ́n to ilé ayé kí ilé ayé lè máa fún régé. Ìtàn tún sọ pé Ọ̀rúnmìlà wà níbí tí àwọn ènìyàn tí Yan ìpín tàbí àyànmọ́, ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè é ní Ẹlẹrìí ìpín. Yorùbá gbagbọ́ pé Ọ̀rúnmìlà mọ ohun gbogbo, ó sì lè wá ojútùú sí gbogbo ohun tí ó bá rú ẹ̀dá lójú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń máa ń bí ifá léèrè tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ohunkóhun.Wọ́n ń pè é ní Akéréfinúṣọgbọ́n, Amọ̀rànmọyè. Ìtàn tún sọ fún wa pé Gbáyé gbọ́run ni Ọ̀rúnmìlà pe Olódùmarè máa ń ránṣé pè é s’ọrun nígbà tí ó wà láyé kí ó wá ràn Ọn lọ́wọ́. Ìtàn sọ pé Ọ̀rúnmìlà ní ìyàwó, ó sì bímo mẹ́jọ àti pé àbíkẹ̀yìn rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́wọ̀ ló wu ìwà àfojúdi , ó kọ̀ láti forí balẹ̀ fún bàbá rẹ̀ tí ó fi bínú padà sí ọ̀run. Ohun gbogbo dojúrú nílé ayé lẹ́yin tí Ọ̀rúnmìlà bínú lọ sí ọ̀run. lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ẹ̀bẹ,̀ Ọ̀rúnmìlà fi èkùrọ́ mẹ́rìndínlogún rọ́pò ara rẹ̀ tí ó di ikín tí àwọn babaláwo ń lò lónìí Lẹ́yìn èyí ni ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí í padà bọ̀ sípò. Àwọn ohun tí a fí ń bọ ifá ní adìyẹ,obì.ìlù ìpèsè àti agogo ni ìlù ifá.Olúwo/Àràbà ni olórí àwọn. Àwọn ohun tí a máa ń bá pàdé ní ilé ifá ní: ọpọn ifá,ikín mẹ́rìndínlógún, ọ̀pẹ̀lẹ̀,ìbò, ìrọ́kẹ́.
  4. Èṣù
    Èṣù wà lára àwọn òrìṣà tí ó fi ẹ̀wọn rọ̀ wá sáyé. Iṣẹ́ rẹ̀ ni a lè fi wé ti ọ̀gá ọlọ́pàá nítorí pé òun ni Yorùbá gbàgbọ́ pé ó máa ń mú àwọn tí ó rú òfin Olódùmarè àti àwọn tí ó bá ń hùwà àfojúdi sí àwọn òrìṣà yòókù tí yóò sì fi ìyà tó tọ́ jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn Yorùbá ṣe àpèjúwe èṣù bí í ẹni kúkúrú, tí ó dúdú fakí, tí ó sì burẹ́wà ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé ere tí ó dúdú tí ìpàkọ́ rẹ̀ gùn sẹ́yìn ni àwọn ẹsìn èṣù máa ń gbé kiri gẹ́gẹ́ bi èrè èṣù. Yorùbá gbà pé aṣeburúkú-ṣerere ni èṣù. Ó fẹ́ràn epo pupa,ó sì kórira àdí. Òkúta yangí tí a dá epo lé lórí ni ojúbọ èṣù.

Iṣẹ́ ṣíṣe
Dáhùn ìbéèrè yií

  1. Kọ orúkọ merin mìíràn tí Ọ̀rúnmìlà ń jẹ́
  2. Kín ní èèwọ̀ èṣù?
  3. Òrìṣà wo ló níṣe pẹ̀lú irin?
  4. Kọ orúkọ mìíràn tí èṣù ń jẹ́?
  5. Kín ni pàtàkì Ọ̀rúnmìlà láàárín àwọn Yorùbá?
  6. Kọ mẹ́ta nínú èèwọ̀ ọbàtálá.

11/06/2020

Ẹ kú u deédé àsìkò yìí ọ ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ mi, mo kí yín kú u iṣẹ́.

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹta

  1. .Daruko apeere irun didi mefa ati Irun kiko méjì nile Yoruba.
    Irun dídì:kòlẹ́sẹ̀, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, kọjúsọ́kọ, ṣùkú, korobá, panumọ́ abbl.
    Irun kíkó: Morèmi, onílé gogoro,ogún parí, láyípo abbl.
  2. Daruko orisii ila oju kiko marun un.
    Pélé,àbàjà, gọ̀ǹbọ́, túré, kẹ́kẹ́, gọ̀ǹbọ́ àti bààmú

3.So awon itesiwaju ti o ti ba asa oge sise lóde òní
(i) Sítàí irun dídì àti kikó fún àwọn obìnrin kò lóǹkà.(bírédì,gẹ́ẹ́rì,wíífúọ̀ọ̀nù abbl)
(ii) ìpara, lọ́fínńdà àti àtíkè lóríṣìíríṣìí ti wà.
(iii) oríṣìíríṣìí ọṣẹ ìbóra ló wà.
(iv) kóòkù, ṣẹ́ẹ̀tì àti ṣòkòtò ti di àṣà aṣọ wíwọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin.
(v)ìmúra àwọn ọmọge lóde òní kọjá sísọ,ìdajì ara ni wón fi sílẹ èyí kò sì bójú mu rárá.
(ví) Àṣà ìlà kíkọ́ tí ń di àfìṣéyìn tí eégún fi aṣọ.

Ọ̀sẹ̀ kẹrin
Déètì:11/06/2020
Àkòrí: Àpólà-ìṣe Nínú Èdè Yorùbá

Àpólà-ìṣe ni òpómúléró fún gbólóhùn èdè Yorùbá. Ìdí nì yìí tí ó fi jẹ́ dandan fún gbogbo gbólóhùn èdè Yorùbá láti ní i. Àpólà-ìṣe ni ó máa ń sọ ohun tí olùwà ṣe.
Àpólà-ìṣe nínú èdè Yorùbá lè jẹ́:
(a) ẹyọ ọ̀rọ̀ ìṣe pọ́nńbélé: irú ọ̀rọ̀ ìṣe báyìí máa ń dúró nígbà mìíràn gẹ́gẹ́ bíi odidi gbólóhùn,a sì máa ń fi wón pàṣẹ ni. Bí àpẹẹrẹ:

dìde
Lọ
Jókòó

(b) ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe àti àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ:
Ọ̀rọ̀ ìṣe àbọ̀
ra ẹ̀bà
sun Iṣu
pa òkété
kan ìlèkùn

(d) ó lè jẹ́ aṣerànwó ọ̀rọ̀ ìṣe/aṣáájú ọ̀rọ̀ ìṣe àti àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ:
ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Èkó
mọ̀ọ́mọ̀ da omi
jàjà ra aṣọ
ti máa ń gun igi
ń fọ ọwọ́

(e) ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe, àbọ̀ àti ẹ̀yán. Bí àpẹẹrẹ
ra aṣọ pupa
Jẹ ọmọ rere
sun iṣu ewùrà
kọ́ ilé meta
ra ìwé w yìí

(ẹ) ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe àti àpónlé. Bí àpẹẹrẹ
jẹun yó
ga fíofío
pọ́n ràkọ̀ràkọ̀
funfun báláú

(f) ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe, àbọ̀ àti àpólà atókùn. Bí àpẹẹrẹ:
ra iṣu ọjà
gbé abọ́ sókè
rí Adé ní àná
lọ sí Oko

Isé síse
Tọ́ka sí àpólà ìṣe nínú àwọn gbólóhùn yìí
Àpẹẹrẹ: Jídé kọ ebè.
Aṣọ rẹ pọ́n ràkọ̀ràkọ̀.

  1. Wálé ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹun.
  2. Fẹ́mi lọ sí Ìbàdàn.
  3. Wá rí mi.
  4. Igi náà ga fíofío.
  5. Ayọ̀ ń ṣiṣẹ́ nítorí ọmọ.
  6. Adéjọbí máa ń yan bí ológun.
  7. Bàbá Adé kọ pẹ̀tẹ́sì méje.
  8. Bọ́lá jókòó rẹ̀pẹ̀tẹ̀.
  9. Mo ṣubú.
  10. Olú kò gba ìwé náà.

OSE KETA

Deeti: 04/06/2020

Atunse si ise ti a se ni ose to koja.(Ihun silebu)

Ko ihun silebu oro wonyii:

1. bamgboye = KF-N-KF-KF
2. Isenbaye = F-KF-N-KF-KF
3. foniimu = KF-KF-F-KF
4. jagunjagun = KF-KF-KF-KF
5.ogongo = F-KF-N-KF
6. okunrin =F-KF-KF
7.orombo = F-KF-N-KF
8.panla = KF-N-KF
9.bata = KF-KF

10. afefe= F-KF-KF

Ise ose keta

Akori : Oge sise laye Atijo

Oge sise ni a le pe ni ona kan pataki ti awon Yoruba maa n gba lati ri i pe ara ati ayika won dunun wo ni gbogbo igba. Aajo ewa ni oge sise. Orisirisi ona ti a n gba se oge laye atijo ni wonyii:

(i) imototo ara (iwe wiwe)

(ii) osun kikun

(iii) laali lile

(iv) tiroo lile

(v) eyin pipa

(vi) ara finfin

(vii)eti lilu

(viii) ileke lilo

(ix)irun didi

(x)ila kiko

(xi) aso wiwo

(xiii)

ASO WIWO

Aso la n fi bo asiri ihoho eniyan. Yoruba maa n lo aso ni ibamu pelu asiko. Ale pin aso Yoruba si ona meta bayii :

(i) aso ise

(ii) aso iwole

(iii) aso imurode

  1. Awon aso okunrin

(i) aso ise okunrin: ewu penpe pelu sokoto ti ko koja orokun ni awon agbe fi n roko. Eyi ni a n pe ni gberi agbe tabi gberi ode

(ii) Aso iwole okunrin :buba ati sokoto.

(iii) Aso imurode okunrin: Dandogo, Agbada, Sapara, Oyala, Gbariye, Dansiki, Buba. sokoto ni Atu, Kenbe, Kamu, Sooro, ladugbo, Abidan abbl. Fila imurode ni Origi, Ikori, Abeti aja , fila onide.

IMG_20200519_084353.JPG (1600×944)

2. Awon aso obinrin

(i) Aso ise awon obinrin je eyi ti ko le di won lowo lenu ise . won a maa wo yeri penpe pelu agbeko.

(ii) Aso iwole obinrin: awon obinrin a maa ro iro ati buba .

(iii) Aso imurode obinrin: Iro, buba, gele, iborun ati ipele.

Rí i pé ọ kọ iṣẹ́ yìí sílẹ̀ sínú ìwé Yorùbá rẹ tí ò ń lò ní kíláàsì. ) IRE OO!

Die ninu awon aso ti a fi n da orisiirisii aso ni ile Yoruba ni aso ofi bi i;

sanyan, etu, kijipa, aran, alaari, petuje abbl.

Ise sise

  1. Daruko apeere irun didi mefa ati Irun kiko méjì nile Yoruba.
  2. Daruko orisii ila oju kiko marun un.
  3. So awon itesiwaju ti o ti ba asa oge sise lode oni.
No Fields Found.

OSE KEJI
Deeti:27/05/2020

Atunse si ise ti a se ni ose to koja.

oroipin si silebuiye silebu
1.ojukokoroo/ju/ko/ko/romarun un
2.sunsunkan
3.dundudu/n/dumeta
4.isalei/sa/lemeta
5.alainironua/la/i/ni/ro/numefa
6.onijagidijagano/ni/ja/gi/di/ja/ganmeje
7.alantakuna/la/n/ta/kunmarun
8.gbagbakan
9.ifei/femeji
10.jokoojo/ko/ometa

Ise ose keji
Deeti : 27/05/2020
Akori Eko:Ihun silebu/ Batani silebu


Ihun tabi batani silebu ni ona ti a fi se akojopo oro inu silebu. Awon Ihun/batani oro onisilebu kan ni wonyii:
1. Ihun silebu le je eyo faweli nikan (F) : Iru faweli yii le je faweli airanmupe (a,e,e,i,o,o) ati aranmupe (an,en,in,on). Bi apeere:
(i) E wa ni ola.
(ii) Mo kan an nikoo.
(iii) O ti jade.
(iv) Ade ri i.

  1. Ihun silebu le je akanpo konsonanti ati faweli. (KF) bi apeere:
    (i) gb + a =gba
    (ii) l + o += lo
    (iii) s + un = sun
    (i) gb + on = gbon
  2. ihun silebu le je konsonanti aranmu asesilebu.(N)

i) ko/n/ko

(ii) du/n/du
(iii) n lo


Ise sise

Ko ihun awon oro yii jade. Apeere:

(i) isale = F-KF-KF

(ii) babalawo = KF-KF-KF-KF

(iv) gende = KF-N-KF

(v)nla = N -KF

Ko ihun silebu oro wonyii:

1. bamgboye
2. Isenbaye
3. foniimu
4. jagunjagun
5.ogongo
6. okunrin
7.orombo
8.panla
9.bata

10. afefe

No Fields Found.

No Fields Found.

OSE KIINI

Deeti :21/05/2020

Akori Eko: Atunyewo Silebu

E ku u deede asiko yii o eyin akekoo mi, a ku ifarada, emi wa a la a ja o.Amin .E je ki a lo asiko yii daadaa.

E je ki a se atunyewo akori eko yii: Silebu

ki ni Silebu?

Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade lekan soso.

Bi apeere:

Oroipin si silebuiye silebu
1. tatasilebu kan
2. ilui/lusilebu meji
3. okunrino/kun/rinsilebu meta
4. agbalagbaa/gba/la/gbasilebu merin
5. isenbayei/se/n/ba/yesilebu marun

ISE SISE

Pin awon oro yii si silebu.

  1. ojukokoro
  2. sun
  3. dundu
  4. isale
  5. alainironu
  6. onijagidijagan
  7. alantakun
  8. gba
  9. ife
  10. jokoo

Dahun ibeere re nipa titele ilana isale yii. Jowo ri i daju pe o ko oruko ise(Yoruba) sinu akamo yii.

No Fields Found.
No Fields Found.