02/09/20.
Itesiwaju Isori Oro (oro-aponle)
Oro -aponle: ni awon oro ti a maa n lo lati fi itumo kun oro-ise. O maa n salaye bi a ti se oro-ise. Bakan naa, o maa n fi irisi oro-ise han. Oniruuru ni oro-ise to wa ninu ede Yoruba, die lara won niwonyi;
.waduwadu
.kiakia
.raurau
.patapata
.janjan
Apeere:
(1). Kunle jeun waduwadu nile oninaawo.
(2). Igi maa jona raurau.
(3). Omi ti tan patapata.
Ise–sise
Lo awon oro-aponle wonyii ni gbolohun kookan.
(a) rokoso
(b) kekere
(d) gegere
19/08/20.
Itesiwaju Isori Oro-(oro-ise)
Oro- ise ni a n pe ni koko gbolohun tabi opomulero gbolohun. Bakan naa, oro-ise oro ti o maa n toka isele ti o sele ninu gbolohun. Oro-ise a maa wa ni eyo oro kan, won si maa n ni itumo kikun. Nigba miiran ori-ise a maa wa laarin oluwa ati abo.
Apeere:
1.Olu pa eku.
2. Kunle je isu.
3. Ayo na Tope.
Ninu awon gbolohun oke yii, Pa, je ati na je oro-ise.
Ko gbolohun ede Yoruba marun-un lati fi oro-ise han ninu won.
12/08/20.
E ku deede asiko yii o. Se daadaa ni gbogbo ile wa? E ku ojo meji meta o. Wonyii ni ise sise lori oro-oruko ti a gbe yewo sehin.
Ise sise
ko gbolohun meta-meta fun oro-oruko ni awon ipo wonyii;
- ipo oluwa
- ipo abo
- ipo eyan
Oro apejuwe: eyi ni awon oro ti a maa n lo lati fi se apejuwe awon oro-oruko ninu apola oruko bakan naa oro apejuwe maa n tele oro-oruko ti o ba n yan. Apeere ni: dudu, funfun, pupa, tutu, giga, kekere, gbigbona, nla, kukuru, abbl.
Fun apeere:
- Iya Ade je eko tutu.
- Aso funfun ni olojo ibi wo.
- Mo mu omi gbigbona.
Awon oro ti a fala si nidii je oro apejuwe.
22/07/20
Itesiwaju oro-oruko
(a) Oluwa: eyi ni oluse isele ti o sele ninu gbolohun(performer of an action).
Apeere:
(i) Baba gbin isu
(ii) Iya ra aso
(b) Abo:eyi ni olufaragba isele ti o sele ninu gbolohun tabi olufaragba nnkan ti oluwa se ninu gbolohun (reciever of an action).
Apeere:
(i) Baba gbin isu
(ii) Iya ra aso
(d) Eyan:eyi ni lilo oro-oruko kan lati fi yan oro-oruko miiran (adjective).
Apeere:
(i) Eja panla ni mo ra.
(ii) Aja ode pa oya.
15/07/20
Atunse si ise ose to koja
- C
- D
- D
- D
- B
ISORI ORO
Awon isori oro je isori ti a ri ninu gbolohun tabi awon isori ti a le pin gbolohun ede Yoruba si. Lara won lati ri oro-oruko ti a o maa gbe yewo lonii.
Oro-Oruko: o le je oruko eniyan tabi nnkan ti kii se eniyan, oruko nnkan to lemii tabi nnkan ti ko lemii. O tile le je oruko nnkan afokanro tabi afoyemo ti ko se e dimu. Amo oriki gboogi kan ti fun oro-oruko niyii: oro-oruko ni orokoro ti a le lo nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun ede Yoruba.
Apeere
- Bola gba iyara re.
- Aja je eegun
- Mo je eyin awo
Akiyesi
Bola ti a fala si nidii je oro-oruko nipo oluwa, eegun je oro-oruko nipo abo nigba ti awo je oro-oruko nipo eyan.
01/07/20
Atunse si ise ose to koja.
Awon ayeye ti a ti le ri ilu lilu ni: ayeye ikomojade, igbeyawo, ile sisi, oye jije, ojo ibi, isinku agba abbl.
Oge sise
Iran Yoruba ni o ni oge sise. Awon Yoruba ni aloye ninu aso wiwo. Tokunrin –tobinrin won ni o gbo faari. Iran Yoruba kii kan wo aso lasan. Aso ti Yoruba ba wo a maa ni itumo. Oto ni aso obinrin, oto si ni aso okunrin.
Aso okunrin
Lara awon aso ti okunrin Yoruba maa n wo lo si ode ayeyeni : agbada, buba awotele,sokoto sooro . A tun ni dansiki, kafitaani, dandogo, gbariye. Awon fila ti won maa n de ni: abeti-aja, akori,labandaka, tajia, ati oribi.
Aso Obinrin
Lara awon aso ti obinrin maa n wo ni; Iro, Buba, Iborun, Ipele, ati gele. Lara won awotele obinrin ni; Tobi, Yeri, Agbeko, ati abbl.
23/06/20
Ise ilu lilu
Awon kan wa ti o je pe ise irna won ni ilu lilu. Awon iran yii ni a n pe ni Ayangalu. Awon idile onilu ni o maa n so omo won ni Ayanyemi, Ayansola, Ayanronke, Ayangbemi abbl. Ni aye atijo ni ile Yoruba, kii se ilu lilu ni awon onilu maa n se, won tun maa n se ise miiran ni opo igba. Okunrin ni o ni ise ilu lilu ni awujo Yoruba. Orisiirisii ilu to wa ni; dundun, bata, agree, benbe,apesin,kiriboto, gudugudu,igbin abbl.
Awon ohun elo ilu sise
- Awo ewure
- Kokogun
- Igi omo
- Saworo abbl
ise sise
daruko awon ayeye ti a ti le ri ilu lilu.
17/0620.
Idahun si ibeere ose to koja
Orisiirisii niawon ounje ti Eledua fi jinki awa omo adarihurun. Asiko si wa fun okookan won lati ri won lori ate. Bi o tile je pe, awon miiran wa ti a maa n ri loorekoore.
Lara awon ire oko ti o wopo lasiko ojo niwonyii:
- efo tabi ewebe lorisiirisii
- oniruuru eso bi i agbalumo,mongoro, igba(ikan), osan abbl
- agbado,isu, ata , tomato ati oniruuru awon nnkan miiran ti enu n je.
Lara awon ire oko ti o wopo lasiko eerun ni:
- ogede agbagba, osan, koko,eyin,abbl.
Ni ose to koja, a soro nipa awon agbe olohun ogbin, lose yii, a o maa soro lori awon agbe olohun osin.
Awon agbe olohun osin la mo si awon agbe ti won n sin oniruuru eran abiye bi i adiye, tolotolo,awo, pepeye abbl. Bakan naa, ewure, agutan,maluu, eja, igbin, ehoro abbl. Awon ti won n sin awon nnkan wonyii yala fun jije tabi fun tita ni a mo si agbe olohun osin.
Awon wonyii lo n pese orisiirsii eran ati eyin ti a n je lati se ara wa loore.
Ise sise
Yato si awon ohun osin ti a ti menu ba loke yii, gbiyanju lati daruko awon ohun osin meta miiran ti a le sin yala fun jije tabi tita.
10/06/20.
Ise Abinibi Ile Wa.
Ni ile Yoruba, orisiirisii ise abinibi lo wa. Lara won ni; ise agbe, ise ilu lilu, ise agbede, ise epo fifo, ise ile mimo, ikoko mimo ise onidiri,abbl. Eyi ti a maa koko gbe yewo ni ise agbe.
ISE AGBE
Ise agbe je ise to gbajugbaja julo laye atijo ni ile Yoruba. ko fere si ile ti a ko ti ni ri agbe ni ile Yoruba nitori pe awon agbe ni o n pese ohun jije gbogbo. Ti ounje ba si ti kuro ninu ise, ise buse. Laye atijo, okunrin nikan lo maa n se ise agbe, asiko ikore nikan ni awon obinrin maa n lo se iranlowo fun won lati ba won kore awon ohun ogbin ti won gbin.
AWON OHUN ELO FUN ISE AGBE
- ile to dara fun nnkan ogbin
- awon ohun ogbin lolokan-o-jokan bi i:agbado, igi ege, eebu isu, iho efo, ata, koko, mongoro, osan, abbl.
- awon ohun elo agbe(irinse agbe) ni:ada, oko, akoro, agbon/apere.
Asiko ojo ni awon agbe maa n gbin ohun ogbin, nitori pe ojo ni o maa n mu ohun ogbin dara.
Ise sise
- daruko ire oko ti o maa n jade lasiko ojo
- daruko ire oko ti a maa n ri lasiko eerun.
03/06/20
Mo fi asiko yii lu Oladiran Semiloore ati Olawaye Segunfunmi ni ogo enu, mo ri owo yin e ku ise o.
Gbolohun Alakanpo
Gbolohun alakanpo ni gbolohun meji tabi ju bee lo ti a fi oro asopo kan so papo di gbolohun eyo kan. Apeere awon oro asopo ti a n lo ni ‘pelu’, ‘amo’, ‘tabi’, ‘sugbon’, ‘yala’, ati bee bee lo.
Apeere
- Tunde je eran adiye sugbon eja panla Tolu je.
- Kola lowo pupo amo ko lawo.
- Bolu ati Bola ni won je eran naa.
Ise sise
Lo awon oro asopo wonyii lati ko gbolohun alakanpo.
‘tabi’, ‘pelu’ ‘yala’ ‘oun’ ati ‘sugbon’.
No Fields Found.27/05/20.
E ku ojumo o eyin akekoo. O da mi loju pe alaafia e wa. Wonyii ni idahun si awon ibeere ise ose to koja.
- Orisii litireso meji lo wa.
- Okookan pin si isori meta.
- Ede je ona ti a n gba gbe ero okan wa jade fun awon elomiran.
- (i) Ede lilo maa n je ki tita ati rira rorun. (ii) O maa n je ki irepo wa. (iii) O maa n je ki a gbo ara wa ye abbl.
- Oruko onkowe iwe Subu-Sere ni Lasunkanmi Tela.
GBOLOHUN ELEYO ORO-ISE
Gbolohun: gbolohun ni akojopo oro tabi eyo oro ti o ni itumo, ti o si ni ise ti o n je nibikibi ti o ba ti je jade.
Gbolohun Eleyo Oro-Ise: eyi ni gbolohun ti kii ni ju eyo oro-ise kan lo ninu re. Oun naa ni a mo si gbolohun abode tabi gbolohun kukuru.
Apeere:
- Motunrayo gba ile.
- Mama mi lo si oja-oba lanaa.
- Awon akekoo wa ni asiko isinmi.
Awon oro ti a fala si nidii je oro-ise, eyi fihan pe oro-ise kookan lo wa ninu awon gbolohun oke yii.
Ise-sise
- ko apeere marun-un fun gbolohun eleyo oro-ise.
- Oruko miiran fun gbolohun eleyo oro-ise ni ………
20/05/20.
E ku u deede asiko yii o eyin akekoo mi. A ku afarada asiko yii, Oluwa yoo maa ko wa yo o amin. Mo ni gbagbo pe e n se ara yin lojo (staying safe). Wonyii ni awon ise ti a o maa gbe yewo fun ti asiko yii, e ri daju pe e mura si ise yin daadaa.
AKORI EKO FUN SAA KETA
AKOONU (CONTENTS)
- Agbeyewo ise saa to koja
- Gbolohun eleyo oro-ise/abode
- Gbolohun alakanpo
- Ise Isenbaye: Ise Agbe
- Ise Isenbaye: Ise Ilu lilu
- Oge sise
- Isori Oro: oro-oruko; oro-apejuwe; oro-ise ati oro aponle.
- Agbeyewo Eko
- Idanrawo
Iwe Litireso Kika Ti Ijoba Yan
Atiteebi lati owo Diipo Gbenro.
Agbeyewo ise saa to koja
Dahun awon ibeere wonyii lori awon ise ti a gbe yewo ni saa to koja.
- Orisii litireso meloo lo wa?
- Daruko isori ti okookan pin si
- Kinni Ede?
- Daruko meji lara iwulo ede
- Ta a ni o ko iwe Subu-Sere?
Jowo ri i daju pe o ko oruko ise (Yoruba) sinu akamo ti a pese fun idahun awon ibeere yii.
IRE O!
No Fields Found.