19/08/20.
Ohun Mimo Ninu Esin Ibile Yoruba (Itesiwaju).
Ti a ba fe wo ohun mimo ninu esin ibile Yoruba,ohun akoko ti a o menuba ni ona ti won n gba sin awon orisa won tokantokan pelu iwa mimo. Won mo eewo orisa won, won o si je dejaa re. Won ki i dale ara won,bee si ni won maa n fi ife ba ara won lo. Awon Olobatala ni o maa n lo nnkan funfun ju. Igbagbo Yoruba ni pe nnkan funfun duro fun ohun mimo. Bakan naa, won maa n samulo omi- ajipon. Omi- ajipon a maa toro. Omi-ajipon yii ni won maa n da sinu amu ti o wa ni ojubo. Gbogbo orisa pata ni ile Yoruba ni o ni eewo. Eewo akoko ti o je mo gbogbo orisa ile Yoruba ni iwa eeri bi i: ole, agbere, pansaga, imele, ojukokoro, okanjua abbl. Eewo orisa kan a maa yato si orisa miiran.
12/08/20.
E ku deede asiko yii o. Se daadaa ni gbogbo ile wa? E ku ojo meji meta o. Wonyii ni awon idahun si awon ibeere ti o koja.
- a
- b
- d
- b
- a
- a
- b
- b
- d
- b
Ohun Mimo Ninu Esin Ibile Yoruba
Ifaara
Awon Yoruba ni esin ti won ki o to di pe esin Kristieni ati Musulumi de. Awon Yoruba ni awon orisa ti won maa n bo. Won gba pe awon orisa wonyii je iranse Olorun Eledaa ti o da ohun gbogbo ti enikeni ko si da. Pelu bi won ti se n ko obi ko orogbo fun awon orisa ti won n sin ohun to, won ni igbagbo ti o gbo pon ninu Olorun Olodumare.
Gbogbo awon orisa wonyii ni o ni ona ti won n gba bo won. Bi won se n bo Sango yato si bi won se n bo Ogun. Koda, ohun eelo irubo orisa kan a maa yato si omiran. Ti Yoruba ba n wa ohun kan ni odo Olorun, ipase awon orisa wonyii ti won je iranse Olodumare ni won maa n to de odo Eledaa.
””’22/07/20
Dahun awon ibeere wonyii lori asa iranra-eni-lowo
Ibeere
- Iye ti a ba da ni a n ko, kii se oro …………….(a) ajo (b)eesu (d)owe
- Iye owo ti won n da nibi esusu maa n ………..(a)po (b) dogba (d)kere
- Ewo ni kii se asa iran- ara-eni-lowo? (a)ebese (b) ajo (d)aso
- …….ati…… ko wa lati ma fi owo meweewa jeun (a)ajo ati aaro(b) esusu ati ajo (d) ebese ati eesu
- Fifi owo pamo si banki dara ju ajo sise lo. (a) beeni (b) beeko
- Ojo ori awon akopa pon dandan ninu ajo dida. (a) beeni (b) beeko
- Awon omo egbe eesu gbodo je ………..(a) olofoofo (b) oloooto (d) alaigboran
- Asa iran-ara-eni-lowo ti o wopo laarin awon onisowo ni (a)aaro (b)ajo (d) ebese
- Asa iran-ara-eni-lowo ti o wopo laarin osise ijoba ati onise osu miiran ni (a)aaro (b) ajo (d) alajeseku
- Awon omo egbe ajo maa n ni ipade. (a) beeni (b) beeko
15/07/20.
Egbe Alajeseku Ode Oni
Orisiirisii ilosiwaju ati idagbasoke ni o ti ba eto oro-aje wa nipa imo-ero sayensi ati asa olaju. Nipa bayii, asa iran-ara-eni-lowo igbalode nipase eto bii a-n-ya-ni-lowo-fi-owo-pamo ni o gbode kan. Apeere won ni:
- ile ifowopamo igbalode, bankii
- egbe alajeseku
- owo ele yiya
- rira oja san-an-die-die
- ajo dida laarin awon ore tabi osise nibi ise ise kan naa.
Ise sise
Gbiyanju lati se akosile awon eto iran-ara-eni-lowo miiran ti o mo yala lati odo ijoba tabi awon ajo ti kii se ti ijoba.
08/07/20.
Esusu/Eesu
- asa fifi owo pamo lati fi se iranlowo lo jemo
- o maa n ni olori esusu
- ile olori esusu ni ipade tabi ijokoo ti maa n waye
- o maa n ni ojo ati akoko ipade
- iye kan ni pato ni owo eesu maa n je
- olori esusu ki i ko owo lowo, nitori bi won ba se n da a ni yoo maa ko o fun eni ti esusu kan
- aaye wa fun omo egbe ti o ba ni isoro owo tabi bukata lojiji sugbon ti asiko ko ti i kan an
- won ki i po niye to ajo
- adehun ko gbodo ye ki i esusu ma ba a daru
- owo esusu ki i din
- awon omo egbe esusu mo ara won daradara ki won to ko esusu jo
- olori eesu gbodo je oloooto eniyan
- o seese ki jije ati mimu waye nile olori lati fi kadii esusu
- eni eesu ti ori re fo ki i ba won dasa akogbeyin.
Itesiwaju Asa Iran-Ara-Eni-Lowo II
- Ajo
- Esusu
- Egbe Alajeseku Ode-Oni
Ajo
- Asa fifi owo pamo lati lo ni ojo iwaju ni o jemo
- Ajo maa n ni olori
- Ajo le je ojoojumo, osoose tabi osoosu
- Iye ti eni kookan ba ni, ni yoo maa da gege bi agbara ba se mo.
- Baba / Iya alajo ni yoo maa ya ojule awon omo egbe ajo ni okookan
- Baba / Iya alajo ni o maa n ko owo ajo lowo
- Awon omo egbe saaba maa wa ni agbegbe oja tabi ilu kan naa ki o le rorun fun baba / iya alajo lati gba.
- Owo ajo maa n din nitori ida kan soso ti o wa fun baba / iya alajo gege bi ajemonu
- A ko le gba owo ajo laije wi pe akoko to lati pari ajo
- Eniyan le pa ajo je, ki o si san-an paapo ni ojo iwaju
- Aida-owo tabi iku omo egbe ajo kan soso ke le tu ajo.
- Ajo dida ki i ni ounje ninu
- Won maa n po niye ju esusu lo
- Awon omo egbe ajo ko mo ara won tan
- Olori ajo gbodo je oloooto ati eni ti o se fi okan tan
23/06/20
dahun awon ibeere wonyii:
17/06/20.
Idahun si ibeere ose to koja.
Iyato laarin owe ati aaro
- ko si ise ti a ko le lo owe bibe fun sugbon ise oko ni kan ni a maa n lo aaro fun
- ero pupo / opo eniyan lo maa n je owe sugbon awon perete eniyan ti imo won sokan lo maa n je aaro
- pipese ounje ati nnkan mimu pon dandan ni owe sugbon ko pon dandan ni aaro
- ki i se dandan ni lati da owe pada sugbon dandan ni lati san aaro pada
- aaye wa fun imele /ole sise ninu owe sugbon aaro ko fi aaye gba imele /ole sise
- ko si adehun kan pato ti won maa n tele ninu owe bibe sugbon adehun pato wa ti awon omo egbe aaro gbodo tele
EBESE
Okan lara asa iranra-eni-lowo naa ni ebese je.
- Ebese je mo bibe eniyan ni ise peepee
- O yato si aaro ati owe
- A le je ebese lati fi ran ana eni lowo tabi eni ti ara re ko le (ti o dubule aisan)
- Bale tabi olori tun le pea won okunrin ilu fun ebese lati fi se ise ilu
- Pipese ounje kop on dandan
- Ko pon dandan lati da ebese pada
- O maa n je ki ise ya kiakia
- Awada ati efe maa n jeyo
- Bakan naa, o fi aaye gba ole ati imele sise.
Ise sise
Daruko ijora meta to wa laarin owe ati ebese.
10/06/20.
Ni ose to koja, a se agbeyewo asa iranra-eni-lowo ti a si soro lori owe. Ni bayii, a o maa soro lori aaro .
AARO
- O wopo laarin awon agbe
- Awon akinkanju okunrin ti ojo ori ati ise sise won fere dogba ni yoo ko ara won jo lati da egbe aaro sile
- Won kii po niye bi I owe
- Adehun ti gbogbo omo egbe aaro gbodo tele wa
- Agbayipo ni aaro gbigba maa n tele titi yoo fi kan eni kookan
- O pon dandan lati da aaro pada
- Pipese ohun jije ati mimu bi agbara ba se mo
- O maa n fa ife,irepo ati isokan
- Orisiirisii orin amuseya ati efe maa n jeyo
- Ko fi aaye gba imele ati ole sise.
Ise sise
Daruko iyato maarun-un to wa laarin owe ati aaro.
03/06/20.
Mo fi asiko yii lu Odekunle Oyinkansola ati Omole Oluwaseyi ni ogo enu, mo ri owo yin, e ku ise o.
Atunse si ise ose to koja.
- Oyin; didun didun la n ba ile oloyin aye re yoo maa dun bi oyin, a ki i foyin senu ka tu u danu aye re ko ni mo ikoro.
- Orogbo;orogbo lo n gbo ni saye, ko o gbo, ko o to, ko dagba ko o tagba a da.
- Iyo; iyo re e o, iyo ladun obe, a ki i fiyo senu ka tu u danu, aye re yoo niyo,
- Omi; omi la bu mu, omi la bu we, enikan ki i bomii sota, omo araye ko ni binu re o.
- Aadun; a ki i faadun senu ka boju je, aye re ko ni baje, aye re yoo maa dun ni.
ASA IRAN-ARA-ENI-LOWO
Ni aye atijo , orisiirisii ona ni iran Yoruba n gba lati ran ara won lowo. Iru iranlowo bee maa n fa ibasepo ati ifowo-sowopo ti o dan moran laarin awujo nitori pe ‘agbajo owo ni a fi n soya’. Awon asa iran-ara-eni-lowo ti o wopo ni ile Yoruba niwonyii;
- Owe
- Aaro
- Ebese
OWE
- Owe je mo ise sise ; bi apeere egusi fifo ,agbado yiya ,obi kika ,koko wiwo ,abbl
- Dida ojo owe sona ati riran awon ti a be lowe leti lati ma je ki won gbagbe.
- Awon ti o maa n je owe po niye
- Owe wulo lati fi se ise ti o po
- Pipese ohun jije ati mimu pon dandan
- Wofun ni, ko pon dandan lati je owe
- Ko pon dandan lati da owe pada
- O maa n je ki ise ya kiakia
- Orisiirisii orin amuseya ati efe maa n waye
- O fi aye gba imele ati ole sise
- Awon agbe alada-nla ni o maa sabaa be owe lati fi sise ti o po
- Ojo owe kii sabaa bo si ojo oja ki gbogbo oju le pe.
ise sise; gbiyanju lati se iwadii lori aaro ati ebese.
No Fields Found.27/05/20.
E ku ojumo o eyin akekoo. Alaafia ko ni ile wa bi? Ajinde ara yoo maa je fun gbogbo wa o.
Wonyii ni idahun si awon ibeere ise ose to koja.
- Awon Oyo lo maa n sun ekun iyawo
- Awon Igbomina lo ni dadakuada
- Igbese akoko ninu eto igbeyawo laye atijo ni-Ifojusode
- kf-kf-kf-kf
- f-kf-kf-kf-kf.
Asa Isomoloruko Nile Yoruba
Okan pataki lara asa ile Yoruba ni asa isomoloruko je.
Nnkan ayo ati idunnu ni o maa n je fun ebi ti omo tuntun ba wo. Ni aye atijo, ojo keje ni a maa n se isomoloruko omobinrin, bi o ba je omokunrin ni ojo kesan-an ni o se isomoloruko re ni owuro kutukutu. Bi o tile je pe asa olaju ati esin ajeji ti n fa ifaseyin ba eto isomoloruko wa nile Yoruba.
Awon Ohun Elo Isomoloruko
- aadun
- ireke
- oyin
- iyo
- ataare
- obi
- orogbo
- eja-aro gbigbe
- eku
- omi
- oti
- owo abbl.
Won maa n lo okookan awon ohun elo wonyii lati fi se iwure fun ikoko naa.
Ise-Sise
Se alaaye bi a ti se n lo awon ohun elo wonyii fun isomoloruko
- oyin
- orogbo
- iyo
- omi
- aadun.
20/05/20.
E ku deede asiko yii o eyin akekoo mi, a ku ifarada asiko yii, Oluwa yoo maa ko wa yo o amin. Mo ni gbagbo pe e n se ara yin lojo(Staying stafe).
Wonyii ni awon ohun ti a maa gbe yewo fun ti asiko yii.
Akori Eko Fun Saa Keta
- Agbeyewo ise saa to koja
- Asa Isomoloruko
- Asa Iranra-eni-lowo
- Ohun Mimo Ninu Esin Ibile Yoruba
- Ihun Apola Ise
- Akoto Ede Yoruba(Itesiwaju)
- Awon Eka Ede ati Yoruba Ajumolo
- Agbeyewo Eko
- Idanrawo
Iwe Litireso Kika Ti Ijoba Yan
Olu Omo lati owo D.O Adisa
Dahun awon ibeere wonyii lori awon ise saa to koja
- Awon eya ti o maa n sun ekun iyawo ni……
- Awon ………………. lo maa n ko orin dadakuada
- Igbese akoko ninu asa igbeyawo Yoruba ni……….
ko ihun awon oro wonyii
4. babalawo
5.agbedegbeyo
Jowo ri i daju pe o ko oruko ise (Yoruba) sinu akamo ti a pese fun idahun awon ibeere yii.
IRE O!
No Fields Found.