JSS 1 YORUBA LANGUAGE

02/09/20.

Itesiwaju Isori Oro (oro-aponle)

Oro -aponle: ni awon oro ti a maa n lo lati fi itumo kun oro-ise. O maa n salaye bi a ti se oro-ise. Bakan naa, o maa n fi irisi oro-ise han. Oniruuru ni oro-ise to wa ninu ede Yoruba, die lara won niwonyi;

.waduwadu

.kiakia

.raurau

.patapata

.janjan

Apeere:

(1). Kunle jeun waduwadu nile oninaawo.

(2). Igi maa jona raurau.

(3). Omi ti tan patapata.

Isesise

Lo awon oro-aponle wonyii ni gbolohun kookan.

(a) rokoso

(b) kekere

(d) gegere

19/08/20.

Itesiwaju Isori Oro-(oro-ise)

Oro- ise ni a n pe ni koko gbolohun tabi opomulero gbolohun. Bakan naa, oro-ise oro ti o maa n toka isele ti o sele ninu gbolohun. Oro-ise a maa wa ni eyo oro kan, won si maa n ni itumo kikun. Nigba miiran ori-ise a maa wa laarin oluwa ati abo.

Apeere:

1.Olu pa eku.

2. Kunle je isu.

3. Ayo na Tope.

Ninu awon gbolohun oke yii, Pa, je ati na je oro-ise.

Ko gbolohun ede Yoruba marun-un lati fi oro-ise han ninu won.

12/08/20.

E ku deede asiko yii o. Se daadaa ni gbogbo ile wa? E ku ojo meji meta o. Wonyii ni ise sise lori oro-oruko ti a gbe yewo sehin.

Ise sise

ko gbolohun meta-meta fun oro-oruko ni awon ipo wonyii;

  1. ipo oluwa
  2. ipo abo
  3. ipo eyan

Oro apejuwe: eyi ni awon oro ti a maa n lo lati fi se apejuwe awon oro-oruko ninu apola oruko bakan naa oro apejuwe maa n tele oro-oruko ti o ba n yan. Apeere ni: dudu, funfun, pupa, tutu, giga, kekere, gbigbona, nla, kukuru, abbl.

Fun apeere:

  1. Iya Ade je eko tutu.
  2. Aso funfun ni olojo ibi wo.
  3. Mo mu omi gbigbona.

Awon oro ti a fala si nidii je oro apejuwe.

22/07/20

Itesiwaju oro-oruko

(a) Oluwa: eyi ni oluse isele ti o sele ninu gbolohun(performer of an action).

Apeere:

(i) Baba gbin isu

(ii) Iya ra aso

(b) Abo:eyi ni olufaragba isele ti o sele ninu gbolohun tabi olufaragba nnkan ti oluwa se ninu gbolohun (reciever of an action).

Apeere:

(i) Baba gbin isu

(ii) Iya ra aso

(d) Eyan:eyi ni lilo oro-oruko kan lati fi yan oro-oruko miiran (adjective).

Apeere:

(i) Eja panla ni mo ra.

(ii) Aja ode pa oya.

15/07/20

Atunse si ise ose to koja

  1. C
  2. D
  3. D
  4. D
  5. B

ISORI ORO

Awon isori oro je isori ti a ri ninu gbolohun tabi awon isori ti a le pin gbolohun ede Yoruba si. Lara won lati ri oro-oruko ti a o maa gbe yewo lonii.

Oro-Oruko: o le je oruko eniyan tabi nnkan ti kii se eniyan, oruko nnkan to lemii tabi nnkan ti ko lemii. O tile le je oruko nnkan afokanro tabi afoyemo ti ko se e dimu. Amo oriki gboogi kan ti fun oro-oruko niyii: oro-oruko ni orokoro ti a le lo nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun ede Yoruba.

Apeere

  • Bola gba iyara re.
  • Aja je eegun
  • Mo je eyin awo

Akiyesi

Bola ti a fala si nidii je oro-oruko nipo oluwa, eegun je oro-oruko nipo abo nigba ti awo je oro-oruko nipo eyan.

01/07/20

Atunse si ise ose to koja.

Awon ayeye ti a ti le ri ilu lilu ni: ayeye ikomojade, igbeyawo, ile sisi, oye jije, ojo ibi, isinku agba abbl.

Oge sise

Iran Yoruba ni o ni oge sise. Awon Yoruba ni aloye ninu aso wiwo. Tokunrin –tobinrin won ni o gbo faari. Iran Yoruba kii kan wo aso lasan. Aso ti Yoruba ba wo a maa ni itumo. Oto ni aso obinrin, oto si ni aso okunrin.

Aso okunrin

Lara awon aso ti okunrin Yoruba maa n wo lo si ode ayeyeni : agbada, buba awotele,sokoto sooro . A  tun ni dansiki, kafitaani, dandogo, gbariye. Awon fila ti won maa n de ni: abeti-aja, akori,labandaka, tajia, ati oribi.

Aso Obinrin

Lara awon aso ti obinrin maa n wo ni; Iro, Buba, Iborun, Ipele, ati gele. Lara won awotele obinrin ni; Tobi, Yeri, Agbeko, ati abbl.

23/06/20

Ise ilu lilu

Awon kan wa ti o je pe ise irna won ni ilu lilu. Awon iran yii ni a n pe ni  Ayangalu. Awon idile onilu ni o maa n so omo won ni Ayanyemi, Ayansola, Ayanronke, Ayangbemi abbl. Ni aye atijo ni ile Yoruba, kii se ilu lilu ni awon onilu maa n se, won tun maa n se ise miiran ni opo igba. Okunrin ni o ni ise ilu lilu ni awujo Yoruba. Orisiirisii  ilu to wa ni; dundun, bata, agree, benbe,apesin,kiriboto, gudugudu,igbin abbl.

Awon ohun elo ilu sise

  • Awo ewure
  • Kokogun
  • Igi omo
  • Saworo abbl

ise sise

daruko awon ayeye ti a ti le ri ilu lilu.

17/0620.

Idahun si ibeere ose to koja

Orisiirisii niawon ounje  ti Eledua fi jinki awa omo adarihurun. Asiko si wa fun okookan won lati ri won lori ate. Bi o tile je pe, awon  miiran wa ti a maa n ri loorekoore.

Lara awon ire oko  ti o wopo lasiko ojo niwonyii:

  1. efo tabi ewebe lorisiirisii
  2. oniruuru eso bi i  agbalumo,mongoro, igba(ikan), osan abbl
  3. agbado,isu, ata , tomato ati oniruuru awon nnkan miiran ti enu n je.

Lara awon ire oko ti o wopo lasiko eerun ni:

  1. ogede agbagba, osan, koko,eyin,abbl.

Ni ose to koja, a soro nipa awon agbe olohun ogbin, lose yii, a  o maa soro lori awon agbe olohun osin.

Awon agbe olohun osin la mo si awon agbe ti won  n sin oniruuru eran abiye bi i adiye, tolotolo,awo, pepeye abbl. Bakan naa,  ewure, agutan,maluu, eja, igbin, ehoro abbl. Awon ti won n sin  awon nnkan wonyii yala fun jije tabi fun tita ni a mo si agbe olohun osin.    

Awon wonyii lo n pese orisiirsii eran  ati eyin ti a n je lati se ara wa loore.

Ise sise

Yato si awon ohun osin ti a ti menu ba loke yii, gbiyanju lati daruko awon ohun osin meta miiran ti a le sin yala fun jije tabi tita.

10/06/20.

Ise Abinibi Ile Wa.

Ni ile Yoruba, orisiirisii ise abinibi lo wa. Lara won ni; ise agbe, ise ilu lilu, ise agbede, ise epo fifo, ise ile mimo, ikoko mimo ise onidiri,abbl. Eyi ti a maa koko gbe yewo ni ise agbe.

ISE AGBE

Ise agbe je ise to gbajugbaja julo laye atijo ni ile Yoruba. ko fere si ile ti a ko ti ni ri agbe ni ile Yoruba nitori pe awon agbe ni o n pese ohun jije gbogbo. Ti ounje ba si ti kuro ninu ise, ise buse. Laye atijo, okunrin nikan lo maa n se ise agbe, asiko ikore nikan ni awon obinrin maa n lo se iranlowo fun won lati ba won kore awon ohun ogbin ti won gbin.

AWON OHUN ELO FUN ISE AGBE

  1. ile to dara fun nnkan ogbin
  2. awon ohun ogbin lolokan-o-jokan bi i:agbado, igi ege, eebu isu, iho efo, ata, koko, mongoro, osan, abbl.
  3. awon ohun elo agbe(irinse agbe) ni:ada, oko, akoro, agbon/apere.

Asiko ojo ni awon agbe maa n gbin ohun ogbin, nitori pe ojo ni o maa n mu ohun ogbin dara.

Ise sise

  1. daruko ire oko ti o maa n jade lasiko ojo
  2. daruko ire oko ti a maa n ri lasiko eerun.

03/06/20

Mo fi asiko yii lu Oladiran Semiloore ati Olawaye Segunfunmi ni ogo enu, mo ri owo yin e ku ise o.

Gbolohun  Alakanpo

Gbolohun alakanpo  ni  gbolohun  meji  tabi ju  bee lo ti a fi oro asopo kan so papo di gbolohun eyo kan. Apeere awon oro asopo ti a n lo ni ‘pelu’, ‘amo’, ‘tabi’, ‘sugbon’, ‘yala’, ati bee bee lo.

Apeere  

  1. Tunde  je eran adiye sugbon eja panla  Tolu je.
  2. Kola lowo  pupo amo  ko  lawo.
  3. Bolu ati Bola ni won je eran naa.

Ise  sise  

Lo awon oro asopo wonyii lati ko gbolohun alakanpo.

‘tabi’, ‘pelu’  â€˜yala’  ‘oun’ ati ‘sugbon’.

No Fields Found.

No Fields Found.

27/05/20.

E ku ojumo o eyin akekoo. O da mi loju pe alaafia e wa. Wonyii ni idahun si awon ibeere ise ose to koja.

  1. Orisii litireso meji lo wa.
  2. Okookan pin si isori meta.
  3. Ede je ona ti a n gba gbe ero okan wa jade fun awon elomiran.
  4. (i) Ede lilo maa n je ki tita ati rira rorun. (ii) O maa n je ki irepo wa. (iii) O maa n je ki a gbo ara wa ye abbl.
  5. Oruko onkowe iwe Subu-Sere ni Lasunkanmi Tela.

GBOLOHUN ELEYO ORO-ISE

Gbolohun: gbolohun ni akojopo oro tabi eyo oro ti o ni itumo, ti o si ni ise ti o n je nibikibi ti o ba ti je jade.

Gbolohun Eleyo Oro-Ise: eyi ni gbolohun ti kii ni ju eyo oro-ise kan lo ninu re. Oun naa ni a mo si gbolohun abode tabi gbolohun kukuru.

Apeere:

  1. Motunrayo gba ile.
  2. Mama mi lo si oja-oba lanaa.
  3. Awon akekoo wa ni asiko isinmi.

Awon oro ti a fala si nidii je oro-ise, eyi fihan pe oro-ise kookan lo wa ninu awon gbolohun oke yii.

Ise-sise

  1. ko apeere marun-un fun gbolohun eleyo oro-ise.
  2. Oruko miiran fun gbolohun eleyo oro-ise ni ………
No Fields Found.

20/05/20.

E ku u deede asiko yii o eyin akekoo mi. A ku afarada asiko yii, Oluwa yoo maa ko wa yo o amin. Mo ni gbagbo pe e n se ara yin lojo (staying safe). Wonyii ni awon ise ti a o maa gbe yewo fun ti asiko yii, e ri daju pe e mura si ise yin daadaa.

AKORI EKO FUN SAA KETA

AKOONU (CONTENTS)

  1. Agbeyewo ise saa to koja
  2. Gbolohun eleyo oro-ise/abode
  3. Gbolohun alakanpo
  4. Ise Isenbaye: Ise Agbe
  5. Ise Isenbaye: Ise Ilu lilu
  6. Oge sise
  7. Isori Oro: oro-oruko; oro-apejuwe; oro-ise ati oro aponle.
  8. Agbeyewo Eko
  9. Idanrawo

Iwe Litireso Kika Ti Ijoba Yan

Atiteebi lati owo Diipo Gbenro.

Agbeyewo ise saa to koja

Dahun awon ibeere wonyii lori awon ise ti a gbe yewo ni saa to koja.

  1. Orisii litireso meloo lo wa?
  2. Daruko isori ti okookan pin si
  3. Kinni Ede?
  4. Daruko meji lara iwulo ede
  5. Ta a ni o ko iwe Subu-Sere?

Jowo ri i daju pe o ko oruko ise (Yoruba) sinu akamo ti a pese fun idahun awon ibeere yii.

IRE O!

No Fields Found.

No Fields Found.