SS 2 YORUBA LANGUAGE

Atunse si ibeere ise ose kerindinlogun

  1. Dárúkọ bátánì/ ìhun Sílébù tí ó wà.
    (a) fáwẹ̀lì nìkan /F/
    (b) àpapọ kọ́ńsónáǹtì àti fáwẹ̀lì /FK/
    (d)kọ́ńsónáǹtì aránmú asesílébù /N/

2.Kọ ìró kọọkan fún àfipè yìí : afèjìètèpè, : b ,m
aréhọ́n,: r
afàfàséfètèpè,: p,gb,w
aṣẹ́nupè,: t, b, d, k, g
àhanudíẹ̀pẹ̀: e, o
afàjàpè, : y
akùnyùn: b, t,d,m,n, g,gb…..

Pín àwọn ọ̀rọ̀ yìí sí Mọ́fíìmù:
Ìdárò : ì/dá/arò
Ilégbèé: ilé/ ì/ gbé
Ọ̀mùtí: ọ̀/ mú/ ọtí
àìlówólọ́wọ́ : àì/ní/owó/ní/ ọwọ́
Ọmọdekunrin : ọmọdé/ ọkùnrin
akọ̀pẹ : a/ kọ/ ọ̀pẹ
Ìdílé : ìdí/ ilé
Òǹtajà: òǹ/ ta/ ọjà
ẹranko: ẹran/ oko
aláǹtakùn : aláǹtakùn

Ise ose ketadinlogun

Deeti: 10/09/2020

Akori: Awe Gbolohun

Fa àwọn awé gbólóhùn farah tí ó wà nínú gbólóhùn yìí kí ó sì sọ oríṣìí awé gbólóhùn tí ó jẹ́

  1. Màá gbowó tí ó jẹ mí .
  2. Bí ọ bá fẹ́ ọ lè pè mí.
  3. Ó yà mí lẹ́nu pé Adé wá.
  4. Kàkà kí n jalè ma kúkú dẹrú.
  5. Fẹmi tí à ń se rẹ̀ ti dé.
  6. Ọkùnrin kúkúrú tí Adé ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti kú.
  7. Àpínké tí ó sùn ti dìde.
  8. Ó dá mi lójú pé ọmọ náà wà láàyè.
  9. Aṣọ funfun tí mo rà dára.
  10. Ajá náà kú nígbà tí ọkọ̀ kọ lù ú.

03/09/2020

Atunse si ibeere ise ose keedogun

  1. Yatọ sí ìyàwó àti ọmọ Ọládẹ̀jọ,awon meta ni osise níle won. Alabi, Bayo ati Oyeladun
  2. Oyeladun lo se Ise omodo
  3. Awon eda inu itan ni :Adio, Abeni, Baba Adio, Oladejo, Adija , Oyeladun, Bosipo, Alabi, Adu, Bayo
  4. Adio lo mu okele eba dani to o n reti obe
  5. Abeni ni Dokita ti o wa se itoju oun ni Oladejo
  6. Baba Adio ni o mura bi eegun
  7. Adio gbo pe oga re fe da a duro lenu ise lai mo idi re eyi lo fi sare lo si ile awon oga re lati lo mo idi abajo.
  8. Oyeladun ko le lo si ile eko nitori pe awon obi re ko ri owo lati ran an lo.
  9. Oyèládùn bá Bosipo ṣe iṣẹ́ ìṣirò?
  10. Ẹ̀ṣẹ̀ ti Ọládẹ̀jọ ní Àdìó se ni jiji eru oun ko, o si tun ro ejo oun fun awon onibode

Ise ose kerindinlogun

Deeti: 03/09/2020

Akori: Eto iro

Ise sise

  1. Dárúkọ bátánì/ ìhun Sílébù tí ó wà.
  2. Kọ ìró kọọkan fún àfipè yìí : afèjìètèpè, aréhọ́n, afàfàséfètèpè, aṣẹ́nupè, àhanudíẹ̀pẹ̀, afàjàpè, akùnyùn
  3. Pín àwọn ọ̀rọ̀ yìí sí Mọ́fíìmù:
    Ìdárò
    Ilégbèé
    Ọ̀mùtí
    àìlówólọ́wọ́
    Ọmọdekunrin
    akọ̀pẹ
    Ìdílé
    Òǹtajà
    ẹranko
    aláǹtakùn

27/08/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹrìnlá

  1. A – àkọsẹ̀jayé
  2. E – àgbẹ̀
  3. E – babaláwo
  4. E – odó gbígbẹ́
  5. A- alágbède
  6. A – ahunṣo
  7. B – àredú o
  8. Ọ̀lẹ
  9. A- àgbẹ̀
  10. A- àjọ
  11. A – san ẹ̀bẹ̀sẹ́ padà
  12. E- orí dífá
  13. B- dàndógó
  14. A- gbérí ọdẹ
  15. A- abìdán
  16. A- fìlà
  17. B- olóólà
  18. E- Òndó
  19. D- ìkòrì
  20. E- ẹ̀kẹ́
  21. B – ayò
  22. D – ọ̀yàyà

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹẹ̀dógún
Déètì: 27/08/2020
Àkòrí: Lítíréṣọ̀ Àpilẹ̀kọ
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí láti inú ìwé kíkà Nítorí Owó

  1. Yatọ sí ìyàwó àti ọmọ Ọládẹ̀jọ, ọ̀ṣìṣẹ́ mélòó ló wà níle won? D
  2. Iṣẹ́ kín ní Oyèládùn lọ ṣe ní ilé àwọn Bọ̀sípọ̀?
  3. Dárúkọ ẹdá ìtàn márùn tó wà nínú ìwé yìí
  4. Ta ni ó mú òkèlè ẹbà dání tó ń retí ọbẹ̀?
  5. Ta ni Àbẹ̀ní pe Ọládẹ̀jọ nígbà tí Bàbá Àdìó bá wọn pé nínú ilé?
  6. Ta ni eégún?
  7. Kín ní ó sáré gbé Àdìó lọ sílé ọga rẹ̀ Ọládẹ̀jọ, lọ́jọ́ tó ti ìrìn àjò dé?
  8. Nítorí kín ni Oyèládùn kò ṣe lọ sí ilé ẹ̀kọ́?
  9. Ta ni Oyèládùn bá ṣe iṣẹ́ ìṣirò?
  10. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Ọládẹ̀jọ ní Àdìó ṣẹ òun tí ó fi fẹ́ dá a dúró?

20/08/2020

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹrinla

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹtàlá

  1. D — onílẹ́tà
  2. E — oníròyìn
  3. D — ṣíṣe ìlapa èrò
  4. A — aṣàpejuwe
  5. É — ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì
  6. A — àròjinlẹ̀
  7. B — jẹ́kí
  8. B — onísọ̀rọ̀ǹgbèsì
  9. D — ará
  10. D — onílẹ́tà
  11. B — ìkíni
  12. D — orí ọ̀rọ̀
  13. A — ajẹmọ ìṣípayá
  14. D — asòtàn
  15. B — ẹ̀yin
  16. D — ọlọ́pàá
  17. E — jẹ́ kí
  18. A — gẹ́gẹ́ bí
  19. D — ìparí
  20. A — aṣàpèjúwé

Déètì: 20/08/2020

Àkòrí: Àṣà ilẹ Yorùbá

  1. Asa ti a fi n mo ise ti omo yoo se ni _(a)akosejaye. (b) ikomojade (d)ifa dida (e) iwure
  2. Ise akoko ti awon baba nla wa koko se ni ise __.(a)aso hihun (b) ila kiko (d)ilu lilu (e) agbe
  3. Aboruboye ooo ni a ki_____. (a)alaro (b)aborisa (d)ode (e)babalawo
  4. Ise ona ni __.(a)aso hihun (b)epo fifo (d) ode sise (e) odo gbigbe
  5. Emu je ara ohun elo ise _. (a)alagbede (b)ode (d)gbenagbena (e)ahunso
  6. Biribiri je ara ohun elo ise __.(a) ahunso (b)alagbede (d)ode (e)agbe
  7. Alaro ni a n ki ni __. (a) arepa o. (b) aredu o (d)aroye o (e) arinpa o
  8. Eni kan ti Yoruba gba pe ko se e ba se ise ajumose ni _.
  9. Eni ti aaro sise pe fun ju ni __. (a) agbe (b)onidiri (d)aso hihun (d)ode. (e)agbede
  10. Iye ti a ba da ni a n ko ki i se oro _.(a)ajo (b)aaro (d)eesu (e)ebese
  11. Iyato laarin ebese ati owe ni pe a ki I (a) San ebese pade (b) San owe pada (d)fi eesu San an pada (e) fi ajo San an pada
  12. Ewo ni o jemo oge sise okunrin? (a) eyin pipa (b) irun Didi (d)laali lile (e) ori fifa
  13. Aso imurode okunrin ni____. (a)iteko (b)dangodo (d) tobi (e)aran
  14. Aso ise fun okunrin ni____. (a)gberi ode (b) dansiki (d)kafutaani (e)kijipa
  15. Orisii sokoto okunrin ni _.(a)abidan (b)kijipa (e)sulia
  16. Okiribi,adiro,ikori ati onide je apeere __(a)fila (b)sokoto (d)buba (e) irun Didi
  17. Awon wo ni o n ko ila oju? (a) alagbede (b)oloola. (d) gbenagbena. (e) onise ona.
  18. ila ooro kookan ni ereke ni ila awin . (a) Egba (b) Ijebu. (d)Ondo (e)Oyo 19.Apeere ila oju kiko ni yii ayafi. (a) keke (b)gombo (d)abaja (e)ikori
  19. Ewo ni ki I se ere osupa ninu ere idaraya wonyii? (a) bojuboju (b)ekun meran (d) bookobooko (e)eke
  20. Ere pataki ti n lo ogbon inu ni _____. (a) arin tita. (b) ayo tita (d) ijakadi. (e ) bojuboju

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹtàlá
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kejìlá

  1. E–asọrégèé
  2. D — àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
  3. É – àsọrégèé
  4. B – àdàpè
  5. E- àfiwé tààrà
  6. A – orin
  7. B — àwítúnwí
  8. A — Àkànlò Èdè
  9. É — ìkíni
  10. A — Àkànlò Èdè
  11. B— oríkì
  12. D — ọdún
  13. B — àfiwé
  14. B — àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
  15. A — àlọ́
  16. E – àsọrégèé
  17. D – Àkànlò Èdè
  18. A – ọdún
  19. B – Ìpolówó ọjà
  20. D – ọ̀rọ̀ akọ́nilénu

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹtàlá
Déètì: 13/08/2020
Àkòrí: Àròkọ
Ìbéèrè Èwo Ni Ìdáhùn

  1. A máa ń rí gbólóhùn ‘ ìpàdé wa bí oyin” nínú àròkọ. (a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
  2. irú àròkọ wo ni “Ayẹyẹ ìgbéyàwó tó ṣojú mi láìpẹ́ yìí.
    (a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
  3. Ohun tí ó ṣe pàtàkì fún ẹni tí ó fẹ́ kọ àròkọ láti ṣe ni (a) mímọ èdè é lò (b) kíkọ àròkọ tó gùn (d) ṣíṣe ìlapa èrò. (e) ṣíṣe àtúnkà àròkọ rẹ̀
  4. Wọ́n kun ara rẹ̀ ní àwọ̀ ewé, bá ni oríṣìíríṣìí iná tí wọ́n fi ṣe ibẹ̀ lọ́sọ̀ọ́ kọjá sísọ jẹ gbólóhùn tí a lè rí nínú àròkọ (a) alápèjúwe. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
  5. Ohun tí kì í ṣaábà wáyé nínú lẹ́tà kíkọ ní (a) àkànlò èdè (b) àlàyé (d) òwe. (e) ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì
  6. Kí aláròkọ tó máa kọ àròkọ rẹ̀, ó wúlò kí ó ṣe (a)àròjinlẹ̀. (b) ìfáàrà (d) àmúlò èdè. ( e) àkọtọ́
  7. Èwo ni kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan ní ìlànà àkọtọ́ ( a) òun (b) jẹ́kí (d) jọ̀wọ́ (e) rántí
  8. Owó kò níran jẹ́ orí àròkọ
    (a) alálàyé. (b) onísọ̀rọ̀ǹgbèsì. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
  9. Ìtàn gbẹ̀fẹ́ ni ìtàn sí (a) àlejò (b) ọ̀gá (d) ará (e) ọkùnrin
  10. ‘ọ̀gá mi ọ̀wọ́n’ jẹyọ nínú àròkọ(a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
  11. ‘ Bàbá mi tòótọ’ nínú àròkọ onílẹ́tà jẹ́ (a) àdírẹ́sì (b) ìkíni (d) ìparí (é) orí ọ̀rọ̀
  12. Nínú lẹ́tà àìgbagbẹ̀fẹ́, ìgbésẹ tó máa ń tẹ̀lẹ́ àdírẹ́sì ni (a) ìkíni ìbẹ̀rẹ̀ (b) ìkíni ìparí. (d) orí ọ̀rọ̀ (e) ìpín afọ̀
  13. Ikú jẹ́ àròkọ(a) ajẹmọ ìṣípayá (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
  14. Ìkòkò tí yóò jẹ ata ìdí tí á ko gbóná jẹ́ àròkọ
    (a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
  15. Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a)ẹ̀nyin. (b) ẹ̀yin. (d) aiye (e)nwọn
  16. Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a) òshogbo (b) ṣhàgámù (d) ọlọ́pàá (e) ọffa
  17. Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a) enia. (b) õrùn (d) ẹiyẹ (e)jẹ́ kí
  18. Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a) gẹ́gẹ́ bí. (b) nígbàtí (d) nítorínaa (e)nlọ
  19. “Màmá rẹ tòótọ’ nínú àròkọ onílẹ́tà lè jẹ́ a) àdírẹ́sì (b) ìkíni (d) ìparí (é) orí ọ̀rọ̀
  20. ‘Gbọ̀ngàn ìlú mi’ jẹmọ́ àròkọ (a) aṣàpèjúwe (b)asòtàn. (d) aṣàríyànjiyàn (e)ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì

06/08/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kọkànlá

  1. 6080= Ẹgbàata ó lé ọgọ́rin
  2. 2800= Ẹgbẹ̀rìnlá
  3. 8200=Ẹgbàarin ó lé igba
  4. 16300= Ẹgbàajọ ó lé ọ̀ọ́dúnrún
  5. 18200= Ẹgbàásàn an o le igba
  6. 8060= Ẹgbàá rin ó lé ọgọta
  7. 2100=Ẹ̀ẹ́dẹ́gbọ̀kànlá
  8. 10400=Ẹgbaarun ó lé irinwó
  9. 4020= Ẹgbaaji ó lé ogún
  10. 8006=Ẹgbàárin o lé mẹfa

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kọkànlá

Déètì:06/08/2020

Akori: Àwọn ọna èdè inú Lítíréṣọ̀

Irú ọ̀nà èdè wo ni ó wà nínú àwọn ìpèdè yìí:

  1. Ìbá ṣe pé ọ̀run ò jìnà,ǹ bá lọ láàárọ̀, ma dé lọ́jọ́ alẹ́. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àsọrégèé
  2. Ẹlẹdẹ ni TỌ́lání. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
  3. Tíṣá gbá ọmọ létí, etí re sì fàya (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àsọrégèé
  4. Mo fẹ́ lọ dáwà tilẹ. (a) Àkànlò Èdè. (b) àdàpè (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àsọrégèé
  5. Ètè rẹ fẹ́lẹ́ bí ọ̀bẹ ìrẹ́lẹ́(a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
  6. Omi kìí sàn kó bójú wẹ̀yìn. (a) ọfọ̀. (b) Àkànlò Èdè. (d) àwítúnwí. (e) ìkíni
  7. Mo wí wí wí, o fàáké kọ́rí. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
  8. Fàáké kọ́rí.(a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
  9. Ojú gbooro ooo.. (a) ọfọ̀. (b) Àkànlò Èdè. (d) àwítúnwí. (e) ìkíni
  10. Fi ọwọ́ fa jọ̀gọ̀dì. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
  11. Wínní wínní lójú orogún. (a) àlọ́ àpamọ. (b) oríkì. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
  12. A díá fún máa jẹyọ nínú a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
  13. Ó dúdú bí kóró isin (a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
  14. Ọ̀bọ ni Ṣọlá. a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
  15. Ọ̀pá tín-ín-rín kanlẹ̀ ó kànrun. (a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
  16. Ayé gbó ọ̀run mọ̀.(a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé

17.Ẹja n bákàn. (a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé

  1. Igba eṣinṣin kì í dènà dowó. (a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé
  2. Láńgbé orí ebè jẹ́. (a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé
  3. Ọ̀bọ ń gbọ́bọ gọ̀pẹ jẹ́
    (a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) ọ̀rọ̀ akọ́nilẹ́nu (é) àsọ̀régèé

30/07/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹwàá

  1. Pọn= ọ̀rọ̀-ìse aṣàpèjúwe, aláìgbàgbọ
  2. pa, jẹ = ọ̀rọ̀-ìse oníbọ̀, ẹlélà
  3. Fa, yà =ọ̀rọ̀-ìse oníbọ̀, ẹlélà
  4. gbé, pọn, gùn=ọ̀rọ̀-ìse àsínpọ̀
  5. Jókòó = ọ̀rọ̀-ìse àkànmọ́rúkọ
  6. Kú, kú = ọ̀rọ̀ ìṣe alápèpadà
  7. Jọ̀wọ́= ọ̀rọ̀ ìṣe apàṣẹ
  8. bí = ọ̀rọ- ìṣe asolùwàdàbọ̀
  9. dá = ̀ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè
    10.ga = ọ̀rọ̀ ìṣe aṣàpejuwe

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kọkànlá
Déètì: 30/07/2020
Àkòrí: Ònkà Yorùbá

(Ẹgbàá dé ọ̀kẹ́ kan)

figoÒnka YorùbáAlaye
2000
Ẹgbàá2000*1
4000Ẹgbàajì2000*2
6000Ẹgbàáta2000*3
8000Ẹgbàárin2000*4
10,000Ẹgbàárùn ún2000*5
12,000Ẹgbàáfà2000*6
14,000Ẹgbàáje2000*7
16,000Ẹgbàájọ2000*8
18,000Ẹgbàásàn án2000*9
20,000Ẹgbàáwàá/Ọ̀kẹ́ kan2000*10

Ó dín tàbí ó le ni a ó máa lò dé orí onkaye tí a fẹ. Àpẹẹrẹ:
20,400=20,000+400 ọ̀kẹ́ kan lé irinwó
2060=2000+60 Ẹgbàá ó le ọgọta
3990=4000-10 Ẹgbaaji ó dín mẹwàá
4002=4000+2 Ẹgbàáji ó lé méjì

Iṣẹ́ ṣíṣe

Ko àwọn fígọ̀ yìí ni Òǹkà

  1. 6080
  2. 2800
  3. 8200
  4. 16300
  5. 18200
  6. 8060
  7. 2100
  8. 10400
  9. 4020
  10. 8006

Ìṣe ọsẹ kẹwàá
23/07/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹsán an

  1. Kín ni ègè dídá? Ègè dídá ni Lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá tí ó wọ́pọ láàárín àwọn Ẹ̀gbá.̀ Ègè dídá jẹ́ ohùn orò.
  2. Agbègbè ìlù wọn ni àwọn Lítíréṣọ̀ alohùn yìí ti wọ́pọ̀?
    (i) rárà: Ọ̀yọ́
    (ii) ègè : Ẹ̀gbá
    (iii) ẹkún ìyàwó : Ọ̀yọ́
    (iv) orin etíyèrí : Ọ̀yọ́
    (v) orin obitun : Òǹdó
  3. Kín ní ìyàtọ̀ tó wà láàárín ègè dídá àti rárà sísun?Ohùn rárà yàtọ̀ sí tí ègè dídá. Àwọn olórò ló ní ègè dídá, àwọn Eléṣù ló sun rárà. Àwọn Ọ̀yọ́, Ìbàdàn, Òṣogbo, Ẹdẹ,Ìgbómínà àti Ìlọrin ni wón máà ń sun rárà. Àwọn Ẹ̀gbá àti Òwú ló ń dígè.
  4. Ìran wò ni adígè? Ìran Lábọ́lá
  5. Òrìṣà wo ni ègè dídá jẹmọ́? Òrìṣà Orò.

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹwàá
Déètì: 23/07/2020
Àkòrí: Orísìí Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ ìṣe

Déètì: 23/07/2020
Àkòrí: Ìtẹ̀síwájú lórí Àpólà ìṣe
Orísìí Ìsọ̀rí ọ̀rọ-̀ìṣe

  1. Ọ̀rọ̀- ìṣe aṣàpèjúwe: irú ọ̀rọ̀ ìṣe yìí ni ó máa tọ́ka sí olùwà.
    Àpẹẹrẹ
    (a) Ọmọbinrin náà kúrú. (Kúrú)
    (b) Iṣu yìí tóbi. (tóbi)
    (d) igi wọn gùn. ( gùn)
    (é) Iṣẹ́ pọ̀. (pọ̀)
  2. Ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè: èyí ni a fi máa ń gbé ìbéèrè kalẹ̀. Méjì péré ni ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè tí ó wà nínú èdè Yorùbá. Àpẹẹrẹ: dà, ńkọ́.
    (a) Àwọn ọmọ ńkọ́? (ńkọ́)
    (b) Aṣọ eégún dà? (dà)
    (d) Ilé yín dà? (dà)
  3. Ọ̀rọ̀- ìṣe apàṣẹ: èyí ni a máa ń saábà lò nínú gbólóhùn àṣẹ nìkan. Àpẹẹrẹ
    (a) Ẹ pẹ̀lẹ́ (pẹ̀lẹ́́)
    (b) Ẹ dákun.(dákun)
    (d) Ẹ kú iṣẹ.́ (kú)
    (e) O káre. (káre)
  4. Ọ̀rọ̀-ìṣe asolùwàdàbọ̀: ọ̀rọ̀ ìṣe asolùwàdàbọ̀ ni èyí tí olùwà àti àbọ̀ le gba ipò ara wọn nínú gbólóhùn. Àpẹẹrẹ:
    (a) Mo bínú. — Inú bí mí.
    (b) Mo jìyà. — Ìyà jẹ mí.
    (d) Ó ṣiwèrè. — Wèrè ṣe é.
    (e) Mo kánjú. — Ojú kán mi.
  5. Ọ̀rọ̀-ìṣe alápèpadà: èyí ni ọ̀rọ̀-ìṣe tí a máa ń ṣe àpètúnpè ọ̀rọ̀-ìṣe kan náà fún nínú gbólóhùn kan. Àpẹẹrẹ:
    (a) Jésù ni a mọ̀ mí mọ̀. (mọ̀)
    (b) Má dá mi dá bùkátà mi. ( dá)
    (d) Ayé kò fẹ́ ní fẹ́ ire. ( fẹ́)
    (e) Kọ́bọ̀ ló kù mí kù. ( kù)
  6. Ọ̀rọ̀-iṣè àkànmọ́rúkọ: èyí ni a ṣá lára àpapọ ọ̀rọ̀ ìṣe àti ọ̀rọ̀ orúkọ. Ó máa ń hàn pé ọ̀rọ̀ orúkọ wà lára ọ̀rọ̀ ìṣe yìí nítorí pé ìṣesí tí ó wà láàárín ọ̀rọ̀ orúkọ àti ẹ̀yán ajórúkọ ni ó máa ń wà láàárín ọ̀rọ̀ ìṣe àkànmọ́rúkọ àti ẹ̀yán ajórúkọ. Àpẹẹrẹ:
    (a) Wọn gbàgbé wa . ( gbàgbé)
    ( b) Bísí pàdée Bọ́lá. (Pàdé)
    ( d) Bàbá náà lawọ́. ( lawọ́)
    (e) Olú ti paná.(paná)
  7. Ọ̀rọ̀-ìṣe aṣokùnfà : èyí ni ó máa ń fa nǹkan tàbí tí ó máa ń mú kí nǹkan ṣẹlẹ̀. Àpẹẹrẹ:
    (a) Ó mú mi ṣe ọ̀gá. (Mú)
    (b)Ó dá ẹ̀rín pa mí. (dá)
    (d) Ó kó ìyà jẹ ọmọ náà. (kó)
    (e)Ó fi ìṣe gún mi lẹ́sẹ̀. (fi)
  8. Ọ̀rọ̀ ìṣe oníbọ̀/ ẹlẹ́là: èyí ni ọ̀rọ̀-ìṣe tí a máa ń fi àbọ̀ Pín sí méjì. Àpẹẹrẹ:
    (a) Ọ̀gá àgbà bá ọmọ wí. (báwí)
    (b) Olú ba àga jẹ́. (bàjẹ́)
    (d) Mo tan Títí jẹ. (tànjẹ)
    (e) Adé rẹ́ mi jẹ. ( rẹ́jẹ)
  9. Ọ̀rọ̀ ìṣe àsínpọ̀: èyí ni ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó bá ju kan,méjì, mẹta lọ nínú gbólóhùn. Àpẹẹrẹ:
    (a) Ìyá Ṣọlá ra iṣu ṣè jẹ. (rà,sè,jẹ)
    (b) Wọn ra ẹ̀pà jẹ. ( rà,jẹ)
    (d) Olú kò tètè gbé àga wa.( kò, tètè, gbé , wá)
    (é) ó ti sùn lọ ṣáájú wa. ( Sùn, lọ, ṣáájú)

(Àkíyèsí pàtàkì: awọn ọ̀rọ̀ ìṣe tí ó wa labẹ isori kọọkan ní ó wà nínú akamọ́()

Isé ṣiṣẹ́
Kọ ọ̀rọ̀ ìṣe inú gbólóhùn ọkan sílẹ, kí ó sì sọ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́

  1. Èso náà pọ́n.
  2. Ìyá pa ẹja jẹ.
  3. Ṣọlá fa ìwé mi ya.
  4. Titi gbé ọmọ pọ̀n gun orí igi.
  5. Ṣọlá jókòó sílẹ.
  6. Ó’ kú alàgbà náà kú kọ́bọ̀.
  7. Ẹ jọ̀wọ́.
  8. Inú bí Òjó.
  9. Ìwọ dà?
  10. Ọmọ náà ga.

Ise ose kesan-an

Deeti : 16/07/2020

Akori: Ege Dida

(AKIYESI: Akekoo kankan ko i ti dahun ibeere ose kejo nitori naa mo fe ki e wa idahun si ibeere naa. E ye idanilekoo ose kejo wo lati fi dahun ibeere isale yii.

Ise sise

Dáhùn àwọn ìbéèrè yií

  1. Kín ni ègè dídá?
  2. Agbègbè ìlù wọn ni àwọn Lítíréṣọ̀ alohùn yìí ti wọ́pọ̀? (i) rárà (ii) ègè (iii) ẹkún ìyàwó (iv) orin etíyèrí (v) orin obitun
  3. Kín ní ìyàtọ̀ tó wà láàárín ègè dídá àti rárà sísun?
  4. Ìran wò ni adígè?
  5. Òrìṣà wo ni ègè dídá jẹmọ́?

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹjọ
Déètì: 09/07/2020
Àkòrí: Ègè Dídá

Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a lè lò nígbà kúùgbà ni ègè dídá jẹ́. Kò sí agbo Lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá tí ègè dídá kò bá mú. Ohùn ègè ni a fi ń pe orò èyí ló mú kí wọn máa ki àwọn Ẹ̀gbá ní ” Ẹ̀gbá ọmọ Adígè sọ̀rọ̀.” Àwọn ewì alohùn tí wọ́n jọ jẹ irú ni rárà,ẹkúnyàwó,orin etíyèrí àti orin obitun.

Ohùn rárà yàtọ̀ sí tí ègè dídá. Àwọn olórò ló ní ègè dídá, àwọn Eléṣù ló sun rárà. Àwọn Ọ̀yọ́, Ìbàdàn, Òṣogbo, Ẹdẹ,Ìgbómínà àti Ìlọrin ni wón máà ń sun rárà. Àwọn Ẹ̀gbá àti Òwú ló ń dígè. Àwọn ìlú mìíran tí ó mú ìsìn orò ní bàbàrà ni Ìbàràpá méjèèjì àti àwọn ìlú díẹ̀ ní ilẹ̀ Èkìtì.

Òpò nǹkan ni rárà àti ègè fi jọ ara wọn, bí a ṣe ń fi rárà ki ọba, ìjòyè àti àwọn jagunjagun bẹẹ náà ni à ń dígè ki ọba, ìjòyè àti àwọn gbajúmọ̀ ìlú.

Ègè Dídá àti rárà sísun kò ní nǹkan kan ṣe pọ̀ mọ́ òrìṣà kankan mọ́ lóde òní kò sì dìgbà tí o bá jẹ́ ọmọ olórò kí ó tó dígè.A rí àwọn tí ó fi ègè dídá àti rárà sísun ṣe iṣẹ́ ṣe, wọn fi ń dárayá, obìnrin ilé gan kò gbẹ́yìn nínú eré ègè dídá pàápàá nígbà tí wọ́n bá ṣẹ́́ ẹ̀gúsí, fọ epo ní ẹkù abbl. Ègè Dídá máa ń mú ìwúrí bá ẹni tí wọ́n bá ń kì.

Oríṣìí adígè méjì ni a lè yika sí láàrin àwọn Ẹ̀gbá, àkọ́kọ́ ni ti ilé LÀBỌ́LÁ . Àwọn ni a bí sílé adígè. Ìsòrí Kejì ní àwọn tó jẹ́ pé kò sí ègè dídá ní ìran wọn,en máa ń kì ègè dídá fún iṣẹ́ òòjó tàbí fún kówó má dilẹ̀. Àwọn àgbàlagbà ní ó máa ń saábà kan ègè dídá nítorí ìrírí, ọgbọn,òye àti làákàyè ní adígè nílò fún iṣẹ́ ègè dídá.

Ise sise

Dáhùn àwọn ìbéèrè yií

  1. Kín ni ègè dídá?
  2. Agbègbè ìlù wọn ni àwọn Lítíréṣọ̀ alohùn yìí ti wọ́pọ̀? (i) rárà (ii) ègè (iii) ẹkún ìyàwó (iv) orin etíyèrí (v) orin obitun
  3. Kín ní ìyàtọ̀ tó wà láàárín ègè dídá àti rárà sísun?
  4. Ìran wò ni adígè?
  5. Òrìṣà wo ni ègè dídá jẹmọ́?

09/07/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ keje

  1. Kín ní orúkọ àwọn ìyàwó ṣàngó?
    Ọ̀sun,Ọbà, Ọya
  2. orin àti ìlù tí a ń lù tẹ̀lẹ́ egúngún ni__ẹsà egúngún tàbí iwì egúngún

3. Kọ orúkọ merin mìíràn tí Ọ̀rúnmìlà ń jẹ́. Ẹlẹrìí ìpín, Akéréfinúṣọgbọ́n, Amọ̀rànmoyè, Àgbọnmèrègún.

4. Kín ní èèwọ̀ èṣù? Àdí tàbí yànkọ

5.Òrìṣà wo ló níṣe pẹ̀lú irin? Ògún

6. Kọ orúkọ mìíràn tí èṣù ń jẹ́?Láaroyè,Láàlú, Aṣeburúkú-ṣerere,Ògiri òkò

7.Kín ni pàtàkì Ọ̀rúnmìlà láàárín àwọn Yorùbá? Iṣẹ́ tí Olódùmarè gbé fún un ni láti fi ọgbọ́n to ilé ayé kí ilé ayé lè gún régé.

8. Kọ mẹ́ta nínú èèwọ̀ ọbàtálá. Ọbàtálá kìí mu omi ìkàsì, kìí mu ẹmu, wúndíá tàbí arúgbó tí kò ṣe nǹkan oṣù mọ́n ló máa ń pọn omi àjípọn sí ojúbo rẹ̀,

02/07/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹfà

  1. Kin ni ààlè? Ààle ni àmì tí wọ́n fi lè ẹrù tàbí èso láti kìlọ fún àwọn olè láti má ṣe mú nǹkan náà.
  2. Dárúkọ nǹkan márùn tí a lè fi pààlè. Àkísà aṣọ, ṣùkù àgbàdo,ìkarahun ìgbín, òkúta,ẹsẹ̀ bàtà, ewé gbígbẹ
  3. Dárúkọ àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ òde òní méje. Ìwé ìròyìn, tẹlifísàn,rédíò, ẹ̀rọ-ayé-lu-jára, lẹ́tà kíkọ,agogo, pákó alárìmọ́lẹ̀ lébàá títì,

Isẹ́ ọsẹ keje

Déètì:02/07/2020

Déètì: 02/07/2020

Àkòrí: Àtúnyẹwò àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá


Àwọn òrìṣà ni aṣojú Olódùmarè ní àárín àwọn Yorùbá. Yorùbá gbagbọ́ pé Olódùmarè tóbi ju kí ẹ̀dá máa kọjú sí I béèrè ohunkóhun lọ, ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń gba ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá kọjá láti lè bá wọn gbé ẹ̀bẹ̀ àti àdúrà wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Olódùmarè.

  1. Ọbàtálá/Òrìṣà Ńlá
    Ẹni akọ́dá láti ọwọ́ Olódùmarè ní, òun sì ni igbákejì Olódùmarè tí a fún ní agbára láti ṣe ojú, imú ẹnu etí àti àwọn ẹ̀yà ara yòókù lẹyìn tí Olódùmarè ti dá ara bọrọgidi tán. Ìdí nìyí tí wọ́n fí ń pè é ni Àlámọ rere. Àwọn arọ,abuké,afọ́jú àti àwọn àkàndá mìíràn ni à ń pè ní Ẹni òrìṣà nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn .
    Òrìṣà tí ó fẹ́ràn nǹkan funfun báláú ni Ọbàtálá.Ẹfun ni wọ́n fí ń kún ilé rẹ̀. Aṣọ funfun nì àwọn olùsin rẹ̀ máa ń lò tí won sì máa ń ta sí ojúbọ rẹ̀. Iyán pẹ̀lú ọbẹ̀ ẹ̀gúsí tí a fi òrí sè àti ìgbín ni oúnjẹ rẹ̀. Ọbàtálá kórira ohun ẹ̀gbin àti èérí nítorí náà kìí mu omi ìkàsì(omi ijọ́ Kejì). Àfẹ̀mọ́júmọ́ ní ojoojúmọ́ ni àwọn ìyàwó òrìṣà níláti pọnmi àjípọn sí ojúbọ rẹ̀. Ẹni náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀dọ́mobìnrin tí kò tíì mọ ọkùnrin tàbí arúgbó tí kò ṣe nǹkan oṣù mọ́.Ẹni náà kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀, kò gbọdọ̀ pàdé ẹnikẹ́ni tàbí wẹ̀yìn. Ìdí nìyí tí ẹni náà yóò fi máa mi aaja kí àwọn èèyàn lè yà kúrò lọnà. Ìlù ìgbìn ni won lù níbi ọdún rẹ̀ Ọbàtálá kórira ìwà èké,àìsòdodo, àti ọ̀dàlẹ̀.
  2. Ògún
    Ìtàn kan sọ pé ògún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òrìṣà tí Olódùmarè rán wá sí ilé ayé tí wọn fi ẹ̀wọ̀n rọ̀ wá láti ọ̀run. Ògún nìkan ló mú àdá lọ́wọ́ tí ó fi la ọ̀nà dé ilé ayé. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè é ni Ọsìn ìmọlẹ̀ . Irin àti ohun tí a fi irin ṣe ni àmì ògún Àwọn ọdẹ, jagunjagun, alágbẹ̀dẹ àti àwọn tí ìṣẹlẹ wọn jẹmọ́ irin ni ó máa bọ ògún. Oúnjẹ tí ògún fẹ́ràn ni ajá,ẹ̀sun iṣu,ẹmu. Màrìwò ni aṣọ ògún. Ìjálá sísun ní orin ògún, ìlù agẹ̀rẹ̀, bàtá tàbí dùndún ni ìlù ògún. Ògún kórira ìbúra èké.
  3. Ọ̀rúnmìlà
    Ọ̀rúnmìlà wà lára àwọn òrìṣà tí ó fi ẹ̀wọn rọ̀ wá sáyé. Iṣẹ́ tí Olódùmarè gbé fún un ni láti fi ọgbọ́n to ilé ayé kí ilé ayé lè máa gún régé. Ìtàn tún sọ pé Ọ̀rúnmìlà wà níbí tí àwọn ènìyàn tí Yan ìpín tàbí àyànmọ́, ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè é ní Ẹlẹrìí ìpín. Yorùbá gbagbọ́ pé Ọ̀rúnmìlà mọ ohun gbogbo, ó sì lè wá ojútùú sí gbogbo ohun tí ó bá rú ẹ̀dá lójú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń máa ń bí ifá léèrè tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ohunkóhun.Wọ́n ń pè é ní Akéréfinúṣọgbọ́n, Amọ̀rànmọyè. Ìtàn tún sọ fún wa pé Gbáyé gbọ́run ni Ọ̀rúnmìlà pe Olódùmarè máa ń ránṣé pè é s’ọrun nígbà tí ó wà láyé kí ó wá ràn Ọn lọ́wọ́. Ìtàn sọ pé Ọ̀rúnmìlà ní ìyàwó, ó sì bímo mẹ́jọ àti pé àbíkẹ̀yìn rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́wọ̀ ló wu ìwà àfojúdi , ó kọ̀ láti forí balẹ̀ fún bàbá rẹ̀ tí ó fi bínú padà sí ọ̀run. Ohun gbogbo dojúrú nílé ayé lẹ́yin tí Ọ̀rúnmìlà bínú lọ sí ọ̀run. lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ẹ̀bẹ,̀ Ọ̀rúnmìlà fi èkùrọ́ mẹ́rìndínlogún rọ́pò ara rẹ̀ tí ó di ikín tí àwọn babaláwo ń lò lónìí Lẹ́yìn èyí ni ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí í padà bọ̀ sípò. Àwọn ohun tí a fí ń bọ ifá ní adìyẹ,obì.ìlù ìpèsè àti agogo ni ìlù ifá.Olúwo/Àràbà ni olórí àwọn. Àwọn ohun tí a máa ń bá pàdé ní ilé ifá ní: ọpọn ifá,ikín mẹ́rìndínlógún, ọ̀pẹ̀lẹ̀,ìbò, ìrọ́kẹ́.
  4. Èṣù
    Èṣù wà lára àwọn òrìṣà tí ó fi ẹ̀wọn rọ̀ wá sáyé. Iṣẹ́ rẹ̀ ni a lè fi wé ti ọ̀gá ọlọ́pàá nítorí pé òun ni Yorùbá gbàgbọ́ pé ó máa ń mú àwọn tí ó rú òfin Olódùmarè àti àwọn tí ó bá ń hùwà àfojúdi sí àwọn òrìṣà yòókù tí yóò sì fi ìyà tó tọ́ jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn Yorùbá ṣe àpèjúwe èṣù bí í ẹni kúkúrú, tí ó dúdú fakí, tí ó sì burẹ́wà ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé ere tí ó dúdú tí ìpàkọ́ rẹ̀ gùn sẹ́yìn ni àwọn ẹsìn èṣù máa ń gbé kiri gẹ́gẹ́ bi èrè èṣù. Yorùbá gbà pé aṣeburúkú-ṣerere ni èṣù. Ó fẹ́ràn epo pupa,ó sì kórira àdí. Òkúta yangí tí a dá epo lé lórí ni ojúbọ èṣù.

5.Ṣàngó
Ọ̀kan pàtàkì ni Ṣàngó Olúkòso jẹ́ láàrin àwọn Òrìṣà Yorùbá.Ṣàngó jẹ́ akọni ènìyàn, jagunjagun tí ó lágbára tí ó sì lóògún. Ìtàn fi yé mi pé ṣàngó ni Aláàfin kẹrin tí ó jẹ ní Ọ̀yọ́ ilé. Ó jẹ́ ọba tí ó lágbára púpọ̀,ó sì ní òògùn tí ó máa ń mú kí iná máa yọ lẹ́nu rẹ̀ bí ó bá ń ṣọ̀rọ̀, ó sì ní òògùn tí ó fi máa ń fi ààrá fa iná sórí ilé àwọn tí ó bá ṣẹ̀ ẹ́. Ìwà ìkà, àìbìkítà, àti apamọlẹ́kún jáyé tí ṣàngó ń jù yìí ló mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ará ìlú dìtẹ̀ mọ́ ọn, tí wọ́n sì rọ ̀lóyè nígbà tí ìnira tí ṣàngó ń fún wọn ti pọ̀ jù fún wọn. Èyí ló mú kí Ṣàngó bínú kúrò ní ìlú tí kò sì rí ẹni tẹ̀lé e àfi ìyàwó rẹ̀ Ọya. Kò pẹ́ tí wọ́n kúrò ní ìlú ní ọya padà lẹ́yìn rẹ̀,èyí ló mú kí Ṣàngó fi ìbínú pokùn so. Ọ̀rọ̀ pé ọba sọ wá di ọ̀rọ̀ ẹ̀fẹ̀ àti tu, èyí sì kó ìtìjú bá àwọn ọ̀rẹ́ Aláàfin Ṣàngó. Èyí ló mú kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wọnyìí lọ kó òògùn tí ṣàngó fi ń fa iná sí ilé ọ̀tá rè, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi ẹdun ààrá faná sórí òrùlé ilé àwọn ọ̀tá ṣàngó tí ó ń sọ pé ọba sọ. Ìbẹrù ṣàngó yìí ló mú kí àwọn ènìyàn yí ohùn padà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé Ọba kò sọ. Ìgbà yìí gan an sì ni iná tó dáwọ́ dúró. Àwọn ìwà líle yìí ló mú kí wọn sọ ọ́ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ.Baba mogbà ní olórí àwọn ẹlẹrìí ṣàngó. Àwọn elégùn ṣàngó máa ń didun, wọn a sì mú ọṣé ṣàngó lọ́wọ́. Ìlù bàtá ni wọn lù. Àwọn ohun tí ẹnu ń jẹ bí í orógbó,obì, àgbò ni wọ́n fí ń bọ ṣàngó.

6.Egúngún
Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá nínú ìgbé ayé mìíràn lẹ́yìn ikú ni ó fa ìdí eégún bíbọ. Wọn gbàgbọ́ pé bàbá àwọn tí ó ti kú kò sùn lọ́run, ó sì lè wá sí ayé gẹgẹ bí ará ọ̀run. Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń pe egúngún ni ará ọ̀run. Ológbojò tàbí Ológbìn-ín ló dá awo egúngún sílẹ̀. Aṣọ tí àwọn egúngún máa ń wọ̀ ni agọ̀ tàbí ẹ̀kú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ni a mọ̀ pé ènìyàn nì ó wà nínú ẹ̀kú iṣẹ́ àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ ni láti máa fi yé àwọn ènìyàn pé ará ọ̀run ni. Ìgbàlẹ̀ ni ilé tí egúngún ti máa jáde wa.Alágbaà ni orúkọ oyè olórí elégùn. Ìlù bàtá ni wọn máa lù tẹ̀lé egúngún pẹ̀lú ẹsà pípẹ́.


Iṣẹ́ ṣíṣe

  1. Kín ní orúkọ àwọn ìyàwó ṣàngó?
  2. Lítíréṣọ̀ alohùn wo ni à ń lò fún egúngún?
  3. Kọ orúkọ merin mìíràn tí Ọ̀rúnmìlà ń jẹ́
  4. Kín ní èèwọ̀ èṣù?
  5. Òrìṣà wo ló níṣe pẹ̀lú irin?
  6. Kọ orúkọ mìíràn tí èṣù ń jẹ́?
  7. Kín ni pàtàkì Ọ̀rúnmìlà láàárín àwọn Yorùbá?
  8. Kọ mẹ́ta nínú èèwọ̀ ọbàtálá.

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹfà

25/06/2020

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún

  1. Dárúkọ ọjà méjì méjì tí a lè lo ọgbọ́n ìpolówó ọjà yìí fún : (i) ìtọ́wò: epo, gaàrí, Oyin, irú, ẹmu
    (ii) èènì ṣíṣe: gaàrí, àkàrà, ẹ̀pà, epo, róbó (iii) lílu aago gbàǹjo gbàǹjo: bàtà, aṣọ, (iv) lílo mọ́tò tí a sọ ẹ̀rọ amóhùnkẹ̀ sí: oogun ibile (epa ijebu agbo jedijedi), ipara (Ero Arike)
  2. Dárúkọ àwọn oúnjẹ tí a lè rí lára àwọn irè oko yìí:
    (i) gbágùúdá: láfún, gaàrí, fùfú. (ii) àgbàdo: ẹ̀kọ, ògì, kókóró, ègbo, túwó (iii)iṣu:iyán,èlùbọ́,dùǹdú,ọ̀jọ̀jọ̀,àsáró (iv)ẹ̀pà: òróró,ẹ̀pà yíyan (v)ọ̀gẹ̀dẹ̀:dòdò,ìpékeré, iyán (vi)ẹ̀gúsí, jógí àlapà, òróró, ọbẹ̀ sísè.

Ọ̀SẸ̀ KẸ́FÀ
Déètì: 25/06/2020
Àkòrí: Ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀

Ìbánisọ̀rọ̀ ni ọ̀nà tí ènìyàn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ń gbà fi èrò inú wọn hàn sí ara wọn lọ́nà tí ó fi yé wọn yékéyéké. Ní ayé àtijọ́ àwọn baba-ńlá wa kì í gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀, wọn gbàgbọ́ pé “gbogbo aṣọ kọ́ là ń sá lóòrùn.” Wọn tún ní àsọ̀kù ọ̀rọ̀ ní íoọmọ mi gbẹ́nà.
Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ní ayé àtijọ́

  1. Lílo Ẹ̀yà Ara Fún Ìbánisọ̀rọ̀
    (i) Ojú: bí àpẹẹrẹ,a lè fi ojú fa ni mọ́ra, kìlọ̀ fún ènìyàn bẹ́ẹ̀ a lè fi nà ènìyàn. Tí a bá mọ́ ènìyàn lójú ìtumò rẹ̀ ni pé a kò gba tiẹ. Tí a bá ṣẹ́ ojú ìtumò ní pé kí ó dákẹ́.
    (ii) Orí: tí a bá mi orí ìtumò rẹ̀ le jẹ́ bẹ́ẹ̀ni,bẹ́ẹ̀kọ́,ó dára tàbí kò dára. O sì tún lè jẹ́ àmì ìkáànú tàbí ìlòdì sí nǹkan.
    (iii) imú: tí a bá yímú,a ń fí ẹni náà ṣẹ̀fẹ̀.
    (iv) Ẹnu: ti a bá yọ sùtì tàbí yẹ̀gẹ̀ ẹnu sí ènìyàn,a ǹ fí ẹni náà ṣẹ̀fẹ̀. A lè fi ẹnu súfèé.
    (v) Èjìká: bí a bá ń báni sọ̀rọ̀ tí a fún tàbí sọ èjìlá ,mo gba ọ̀rọ̀ náà wọlé tàbí mo lòdì sí í.
    (vi) Ẹṣẹ̀: bí a bá fi ẹ̀ṣẹ janlẹ̀, àmì ìlòdì sí nǹkan, títẹ ènìyàn mọ́lẹ̀, à ń kìlọ̀ fún un pé kí ó máa ṣe nǹkan tàbí kí ó dákẹ́.
    (vii) Èèkánná: ṣíṣẹ́ ni léèkánná túmọ̀ sí ìbáwí, ìkìlọ tàbí àkíyèsí.
    (viii) Ọwọ́: bí a bá ṣẹ́ owó sí ènìyàn,a ní kí ó wá tàbí dúró. Tí a bá juwọ́, à ń kí ni tàbí dágbéré. Tí a bá ya owó sí ènìyàn, à ń bú ìyá ẹni náà.
  2. ÌPÀROKÒ
    Àrokò jẹ́ ọ̀nà kan tí à ń gbà bá ara ẹni ṣe ní ayé àtijọ́. Bí àwọn àgbà bá fẹ́ sọ̀rọ̀ àṣírí tí ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ ọ́ fún kò sí nítòsí, tàbí tí wọ́n bá fẹ́ ránṣẹ́ sílẹ̀ ní àṣírí, àrokò ni wọ́n ń lò.
    Àwọn ọ̀nà tí àwọn baba-ńlá wa ń gbà pàrokò ránṣẹ sí ènìyàn nì wọ̀nyí:
    (i) Ìlù lílù: ìlù ni àwọn baba-ńlá wa fí máa ń ránṣẹ sí ojú ogun. Wọ́n máa ń lù ìlù láti fi túfọ̀ òkú àgbàlagbà.
    (ii) Ọ̀pá Àṣẹ: ọba nìkan ni ó ń fi ọ̀pá àṣẹ pàrokò. Ọba máa ń fi ọ̀pá àṣẹ ránṣẹ́ láti fi hàn wí pé òun wà níbẹ̀. Bí ọba bá sí fẹ́ rí ẹnìkan ní kíákíá ọ̀pá àṣẹ ni yóò fi ránṣẹ́ sí í.
    (iii) Owó Ẹyọ: Àwọn babaláwo àti olóriṣà-oko ni wọ́n ń fi owó ẹyọ pàrokò. Ìpè pàjàwìrì lórí kí a fi ojú kan ni ni èyí máa ń túmọ̀ sí.
    (iv) Ìyẹ́ Adìẹ: tí a bá tu ìyẹ́ adìẹ fún ọkùnrin kan, ìkìlọ ni pé kí ó jáwọ nínú níní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú obìnrin.
    (v) Owó Ẹyọ meta: tí a bá dì í ránṣẹ́ sí ẹni kan, ìtumọ̀ ẹ̀ ni pé ẹni náà ti di ẹni ìtanù.
    (vi) Ìgbàlẹ̀: tí a bá fi ìgbálẹ̀ ránṣẹ sí ènìyàn, ẹni tí ó pàrokò ránṣẹ yìí kò fẹ́ rí ẹni tí ó pàrokò náà ránṣẹ́ sí mọ́ nínú ilé rẹ̀.
    (vii) Èèpo igi àti aṣọ pupa: tí a bá fi nǹkan yìí ránṣẹ́ sí ọkùnrin tó wà ní ìdálẹ̀, ó túmọ̀ sí pé oyún tí ó fi sílẹ̀ ní ilé tí bàjẹ́.
    (viii) Àalè: tí wọ́n bá bá ààlè lé igi eléso kan, ìkìlọ̀ nìyí pé a kò gbọdọ̀ ká èṣo náà.

Iṣẹ́ ṣíṣe

  1. Kin ni ààlè?
  2. Dárúkọ nǹkan márùn tí a lè fi pààlè.
  3. Dárúkọ àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ òde òní méje.

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún
18/06/2020

Mo kí Ọládàpọ̀ Tolúwanimí kú iṣẹ́,mo rí iṣẹ́ tí ó ṣe.Mo n retí iṣẹ́ ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ mi tókù.
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹrin.
1a. Níbo ni ilé iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ? Ilé aró
b. Kí ni ohun èlò tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lù irin gbígbóná lórí rẹ̀? Owú
d. Kí ni ohun èlò tí a fí ń fẹ́ atẹ́gùn sí iná agbẹ̀dẹ? Ewìrì
e. Kí ni irin tí ó mú lénu tí a lè fi gé irin mìíràn? Ìkọ́

  1. Níbo ni a tí ń fọ epo pupa àti ṣe ọṣẹ? Ẹbu
  2. Dárúkọ mẹ́fà lára ìlù ilẹ Yorùbá: Àgẹ̀rẹ̀, Bàtá, Gángan, Omele, ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, gbẹ̀du, Agogo, Dùndún
  3. Dárúkọ oríṣìíríṣìí ọdẹ mérin: ọdẹ Aperin, ọdẹ Etilé, ọdẹ Adẹdò, ọdẹ Aṣiṣe, ọdẹ Ajagun

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún

Déètì: 18/06/2020

Àkòrí: ìpolówó ọjà

Ìpolówó ọjà ni àgúnmu òwò. Òun ni pípe ẹni tí yóò sọ ọjà di owó.. ní kíákíá. Ní àárọ̀, ọ̀sán,ìrọ̀lẹ́ ni ìpolówó ọjà máa ń wáyé. Àwọn oúnjẹ bí I ẹ̀kọ mímú , ọ̀ọ̀lẹ̀, àkàrà, ògì,ẹ̀wa ìrẹsì sísè abbl ni wọ́n máa ń polówó ní àárò.Bí ó bá di ọ̀sán, ìpolówó kìí sáábà wo, òòrùn ti máa ń mú, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́jà ni yóò lọ sinmi àyàfi àwọn oloúnjẹ bí í ọsán, àmàlà,fùfú,ekùrù,ẹ̀kọ abbl.
Ní ìrọ̀lẹ́, àwọn ọlọ́jà bíi ẹlẹ́ja, elépo,aláta,alátẹ, aláṣọ́ abbl máa ń kiri.
Èdè Ìpolówó ọjà mìíràn a jáde bíi orin, òmìíràn bíi ọ̀rọ̀ apanilẹ́ẹ̀rín. Bí àpẹẹrẹ

  1. Àgbàdo síse:eerín ooo,pòróǹtò.Láńgbé jinna ooo
  2. Àkàrà: ke-e-n-gbe àkàrà
  3. Iyán: iyán rè é, ọbẹ̀ rè é, ẹ wojú obẹ̀ ẹ múyán oo

Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìpolówó ọjà mìíràn/ọgbọ́n ìpolówó ọjà mìíràn

  1. Àfojúrí,Afọwọ́bà àti ìgbéyèyò
  2. Ìṣíwò àti ìtówò
  3. Èni ṣiṣẹ́
  4. Lilú aago lé ọjà lórí
  5. San díẹ̀díẹ̀ tàbí àwìn
  6. Lóde òní, ìpolówó ọjà tún máa ń wáyé nínú ìwé ìròyìn,rédíò, tẹlifísàn, ìwé pélébé, ẹ̀rọ ayélujára.
  7. Lílo mótò tí a so ẹ̀rọ amóhùnkẹ̀ sí
  8. Ìdíje oríire, ráfùlù títà, ẹ̀bùn pínpín láti ṣe kóríyá fún oníbàárà

Iṣẹ́ ṣíṣe
Dáhùn ìbéèrè yií

  1. Dárúkọ ọjà méjì méjì tí a lè lo ọgbọ́n ìpolówó ọjà yìí fún : (i) ìtọ́wò (ii) èènì ṣíṣe (iii) lílu aago gbàǹjo gbàǹjo (iv) lílo mọ́tò tí a sọ ẹ̀rọ amóhùnkẹ̀ sí(v)
  2. Dárúkọ àwọn oúnjẹ tí a lè rí lára àwọn irè oko yìí:
    (i) gbágùúdá. (ii) àgbàdo. (iii) iṣu (iv)ẹ̀pà (v) ọ̀gẹ̀dẹ̀ (vi) ẹ̀gúsí

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹrin 11/06/2020

Ẹ kú u deédé àsìkò yìí o ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ mi.Mo kí yín kú u iṣẹ́

Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹta


1 ọ̀rọ̀ àyálò àfétíyá
tébù
tíṣà.
bọ́tà
télọ̀
pẹ́nṣù
ráìsì
Ọ̀rọ̀ àyálò àfojúyá
Pétérù
Párádísè
Díákónì
Ẹsítérì

2.fork = fọ́ọ̀kì/fọ́ọ̀kù
tailor – télọ̀
brick – bíríkì
globe – gílóòbù
ink. – yín-ìnkì
razor – réṣọ̀
driver – dírẹ́bà/dírẹ́fà/dẹ́rẹ́bà
hospital – ọsibítù/ọsipítū
minister – mínísítà
messenger – mẹ́séńjà

Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹrin
Déètì: 11/06/2020
Àkòrí: Iṣẹ́ Abínibí

Àṣà iṣẹ́ ṣíṣe jẹ́ àṣà pàtàkì láwùjọ àwọn Yorùbá.
Àwọn baba ńlá wa fẹ́ràn iṣẹ́ púpọ̀,wọ́n sì kórira ìwà ọ̀lẹ tàbí ìmẹ́lẹ́ ṣíṣe. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ‘apá lará ìgúnpá ni iyèkan’ , wọ́n tún ní ‘àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tan ni jẹ.’ Díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ àbínibí Yorùbá ní: iṣẹ́ àgbẹ̀, iṣẹ́ ọdẹ, iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ, iṣẹ́ ọnà (bí i odó gbígbẹ́, igi gbígbẹ́ lére, igbá fínfín abbl), Àró dídá, aṣọ híhun, epo fífọ̀, Irun dídì, òwò ṣíṣe, iṣẹ́ awo(ifá dídá), iṣẹ́ ìlù lílù abbl.


Iṣẹ́ Àgbẹ̀dẹ
Àgbẹ̀dẹ ló ń rọ irinṣẹ́àwọn àgbẹ àti ọdẹ.Àwọn ọkùnrin láti ìdílè ológùn-ún ló ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ iṣẹ́ ìdílé ni láyé ọjọ́un ṣùgbọ́n àwọn èniyàn láti inú ẹbí mìíràn lè kọ́ isẹ́ àgbẹ̀dẹ. Ilé iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ ni a mọ̀ sí ilé arọ́. Gbogbo ohun èlò tí ó jẹmọ́ irin bí i àdá, ọkọ,́ idà, ọ̀bẹ, ìbọn, àáké abbl ni àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń rọ. Àwọn oríṣìíríṣìí isẹ́ àgbẹ̀dẹ ni: Àgbẹ̀dẹ bàbà, àgbẹ̀dẹ dúdú àti àgbẹ̀dẹ òjé. Àwọn irinṣẹ́ alágbẹ̀dẹ ni :owú, ọmọ owú,ẹ̀mú, ewìrì,ìsáná, ìkọ́. Lára èèwọ̀ alágbẹ̀dẹ ni pé wọn kì í súfèé nílé arọ́. Wọn kì í tẹ́wọ́ gba owó,dídà ni ẹni tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ máa da owó sílẹ̀ nílé arọ́.

Epo fífọ̀
Obìnrín ló ní iṣẹ́ ẹyìn ṣíṣí àti epo fífọ̀.Ẹbu ni à ń pe ibi tí wọn ti máa ń fọ epo pupa. Àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń fọ epo pupa ni àwọn ìkòkò omi ńlá bí i merin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú omi, agbada ìdáná,odó, garawa epo,igbá, ihá àti ògùṣọ̀, àpótí ìjokòó, apẹ̀rẹ̀ abbl

Ọṣẹ ṣíṣe
Ẹbu náà ni à ń pe ibi tí àwon ìyá wa ti ń ṣe ọṣẹ dúdú tàbí ọṣẹ àbùwẹ̀.
Àwọn ohun èlò tí a fí ń ṣe ọṣẹ dúdú ni eérú, àdí, tàbí yànkò, aládìro (ìkòkò tí a lù nídìí) agbada,orógùn,ààrò àti Igi ìdáná. Àwọn ìgbésẹ ọṣẹ ṣíṣe nì yìí:
1. Gbé aládìro sórí ìkòkò mìíràn.
2. Da eérú tí a ti jọ̀ dáadáa sínú aládìro.
3. Bu omi sínú eérú tí ó wà nínú aládìro.(omi tí ó ti dàpọ̀ mọ́ eérú yóò máa ro sínú ìkòkò tí ó wà ní ìsàlẹ̀,omi tí ó ń rọ yìí ni à ń pe ní Olúbà).
4. Ṣe Olúbà Títí yóó fí ki.
5. Bu igbá Olúbà méjì pẹ̀lú àdí igbá méjì sínú agbada.
6. Gbé e léná kí o máa rò ó Títí tí yóò fi ki tàbí le.
7. Bí ó bá ti le, o ti di ọsẹ nìyẹn.

Iṣẹ́ ṣíṣe
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
1a. Níbo ni ilé iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ?
b. Kí ni ohun èlò tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lù irin gbígbóná lórí rẹ̀?
d. Kí ni ohun èlò tí a fí ń fẹ́ atẹ́gùn sí iná agbẹ̀dẹ?
e. Kí ni irin tí ó mú lénu tí a lè fi gé irin mìíràn?

  1. Níbo ni a tí ń fọ epo pupa àti ṣe ọṣẹ?
  2. Dárúkọ mẹ́fà lára ìlù ilẹ Yorùbá
  3. Dárúkọ oríṣìíríṣìí ọdẹ mérin

Iṣẹ́ Ọ̀sẹ̀ kẹta
Déètì: 04/06/2020
Ìdáhùn sí ìbéèrè ọ̀sẹ̀ Kejì

  1. Ọbẹ̀ tí baálé kì í jẹ ìyáálé kọ̀ gbọ́dọ̀ se é.
  2. Ọrọ̀-ajé yóò búrẹ́kẹ́ sí i lọ́dún yìí.
  3. Ọ̀rọ̀ náà gbelegẹ́.
  4. Ìgbéraga ní síwájú ìparun.
  5. Àwọn ọmọkùnrin yẹn ni ọ̀rọ̀ náà dá lé lórí.
  6. O múlẹ̀, mófo.
  7. Adégòkè ni igi lẹyìn ọgbà ẹbí rẹ̀.
  8. Bí ẹ̀mí bá wà ìrètí ń bẹ.
  9. Ṣọlá máa ń ṣe àbẹwò lékọ̀ọ̀kan .
  10. Àbọ̀ ọ̀rọ̀ là n sọ fún ọmọlúàbí.

Iṣẹ́ Ọ̀sẹ̀ kẹta
Àkòrí: Ọ̀RỌ̀ ÀYÁLÒ


Ọ̀rọ̀ ayálò ni àwọn ọ̀rọ̀ èdè mìíràn tí a yá wọ inú èdè Yorùbá. Yorùbá máa ń yá èdè Gẹ̀ẹ́sì, Hébérù, Lárúbáwá àti Hausa. Àpẹẹrẹ: tábìlì, àlàáfíà, Pétérù abbl.

Ọ̀nà tí àwọn ọ̀rọ̀ ayálò gbà wọ inú èdè Yorùbá ni nipasẹ ẹ̀sìn, òwò/ètò ọ̀rọ̀-ajé, òṣèlú, àṣà àti ọ̀làjú.
Bí àpẹẹrẹ mọ́ṣáláṣí,Díákónì, mílíọ̀nù,mílíìkì, Gómìnà abbl.

Yorùbá ní ìlànà méjì tí wọn ń gbà yá ọ̀rọ̀ wo inú èdè. Èyí ni:

  1. Ìlànà àfétíyá : èyí ni pípé àwọn ọ̀rọ̀ ayálò ní ọ̀nà tó súnmọ́ bí elédè ṣe pè é. Bí àpẹẹrẹ Bible – Báíbù, table- tébù.
    2.ìlànà àfojúyá : èyí súnmọ́ ìlànà bí àwọn elédè ṣe ń kọ lẹ́tà ọ̀rọ̀ sílẹ̀. Àpẹẹrẹ.table-tábílì, Bible – Bíbélì.

Ìlànà fonọ́lọ́jì tí a fí ń yá èdè níwọ̀n yìí:
(i) níbi tí kọnsónáńtì méjì bá ti jẹyọ tèléra ,fáwẹlì ‘u’ tàbí ‘i’ a jẹyọ láàárín wọn.
Àpẹẹrẹ bread – búrẹ́dì, glass -gíláàsì,.
(ii) kọnsónáńtì kì í parí ọ̀rọ̀ Yorùbá, a lè fi fáwẹ̀lí ‘u’ tabi ‘i’ tàbí kí á gé e kúrú.
Àpẹẹrẹ gum- gọ́ọ̀mù , fail- féèlì, lantern- láńtà, mobil – móbì.


Iṣẹ́ ṣíṣe

  1. Pín àwọn ọ̀rọ̀ ayálò yìí sí àfétíyá àti àfojúyá : tébù, Pétérù, tíṣà, bọ́tà, Díákónì, ráìsì, télọ̀, párádísè, pẹ́nsù, Ẹsítérì.
  2. Kọ bí a ṣe lè yá àwon ọ̀rọ̀ gẹ̀ẹ́sì yìí wọ inú èdè Yorùbá : fork, tailor, brick, globe, ink, razor,driver, hospital,minister, messenger.

(Rí i pé ọ kọ iṣẹ́ yìí sílẹ̀ sínú ìwé Yorùbá rẹ tí ò ń lò ní kíláàsì. ) IRE OO!

No Fields Found.

OSE KEJI

Deeti:28/05/2020

Idahun si ibeere ise ose kiini

Sipeli AtijoAkoto ode oni
1. nwonwon
2. olopaolopaa
3. eniaeniyan
4. oshogboosogbo
5. shagamusagamu
6. kinikiini
7. NigbatiNigba ti
8. GegebiGege bi
9. Fun uFun un
10. OkurinOkunrin

Ise ose keji

Deeti: 28/05/2020

Akori: Aayan Ogbufo

Ogbufo ni eni ti n tumo ede kan si omiran.

Bi a ba n se ogbufo , a ko gbodo maa mu oro ni okookan lati tumo.sise bee yoo so our itumo ti a fe ki o ni nu.

Ri i pee lo akoto to muna doko .Eyi ni yoo je ki o see ka geere.

Lilo itumo erefee ko bojumu ti a ba n se ogbufo owe,akanlo ede ati ewi.Eyi ko ni fun wa ni itumo ti o kun.

Bi apeere:

  1. Manner maketh man.

Iwa rere leso eniyan.

2. The cat was let out of the bag .

Asiri tu

3. The man is very generous

Okunrin naa lawo gan

4. Health is wealth.

Ilera loro.

5.An adult who once fell into a ditch would definitely show is followers a better way.

Agba to jin si koto ko awon ara yooku logbon.

Ise sise

Tumo awon gbolohun yii si ede Yoruba

  1. A soup that a husband hates, the wife should not cook.

2. The economy will be buoyant this year.

3. The issue is a sensitive one.

4. Pride goes before a fall.

5. Those boys are the subject of the controversy.

6. You are chasing the shadow.

7. Adegoke is the backbone of his family.

8. Where there is life there is hope.

9.sola visits once in a blue moon.

10. A word is enough for the wise.

No Fields Found.

OSE KIINI

Deeti : 21/05/2020

Akori Eko: Akoto ode oni

E ku u deede asiko yii eyin akekoo mi, a si ku u ifarada asiko yii. Oluwa a ko wa yo o. Amin. Mo ro yin ki e lo asiko yii daadaa, ki e gbajumo eko yin. E o se aseyori o.(Amin)

E je ki a se atunyewo akori yii : Akoto ode oni

Akoto ni ilana ti o tona ti a maa n tele lati ko ede Yoruba sile . Apeere:

sipeli AtijoAkoto ode oni
aiyeaye
mettameta
Wipewi pe

Ise sise

Se atunko awon oro isale yii si akoto ode oni.

sipeli atijo Akoto ode oni
1. nwon
2. Olopa
3. Enia
4. Oshogbo
5. Shagamu
6. Kini
7. Nigbati
8. Gegebi
9. Fun u
10. Okurin

Dahun ibeere re nipa titele ilana isale yii. jowo ri i daju pe o ko oruko ise (Yoruba) sinu akamo isale yii.

No Fields Found.
No Fields Found.