20/08/2020
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹtàlá
- D — onílẹ́tà
- E — oníròyìn
- D — ṣíṣe ìlapa èrò
- A — aṣàpejuwe
- É — ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì
- A — àròjinlẹ̀
- B — jẹ́kí
- B — onísọ̀rọ̀ǹgbèsì
- D — ará
- D — onílẹ́tà
- B — ìkíni
- D — orí ọ̀rọ̀
- A — ajẹmọ ìṣípayá
- D — asòtàn
- B — ẹ̀yin
- D — ọlọ́pàá
- E — jẹ́ kí
- A — gẹ́gẹ́ bí
- D — ìparí
- A — aṣàpèjúwé
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kejìlá
- Àáró : Èyí jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n fi máa ń ran ara wọn lọwọ. Àṣà yìí ni wón fi máa ń ṣe iṣẹ́ lóko lọnà tí kò fi ní í pa wọn láyà. Àwọn tí wọn bá kó ara jọ fún àáró gbọdọ jẹ àwọn tí wọn ní agbára dọgba tí wọn ni oko sí itòsí ara wọn. Wọn a máa bá ara wọn ṣiṣẹ nínú oko Títí a fi yí kan gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ àáró. Inú oko ẹni tí àáró bá yí kàn ní wọn tí máa jẹun àáró àti t’ọsan kí iṣẹ́ lè yá.
- owó èlè: ẹni tí ó bá ní ìnáwó pàjáwìrì tí kò sì ní owó lọwọ ni ọ máa yá owó èlé. Ẹni tí yóò yáwó gbọdọ sọ ìgbà tí yóò San an . Bí ọjọ tí yóò San padà bá ṣe pọ tó ní èlé orí owó rè yóò ṣe pọ tó. A fí nǹkan bí dúkìá dógò titi tí yóò fi san owó tí ó yá tan.
- Ilemoṣu: èyí ni kí obìnrin tí a ti sìn lọ sí ilé ọkọ (ṣe ìgbéyàwó) wá pada lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ máa gbé.
- Ìsingbà: ẹni tí ó yá owó tí ó wá ń ṣíṣe sìn olowo ni ó ń singbà tí a sì mọ sí ìwọ̀fà/asingbà. Ó le jẹ́ ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé tàbí àgbà. Ìgbà kúgbà tí ẹni tó yáwó yìí bá rí I San ni yóò tó bọ́ lóko ìsingbà.. Bí ẹni tó yáwó kò bá rí ẹni fi ṣọfà ó lè máa ṣíwọ́-iṣẹ́ rẹ̀ láti lọ ṣíṣe sìn olówó rẹ̀ láti lọ ṣiṣẹ́ sìn olówó rẹ̀ bí ẹ̀ẹ̀mejì tàbí ẹ̀ẹ̀mẹta láàrin ọsẹ.
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹtàlá
Déètì: 13/08/2020
Àkòrí: Àròkọ
Ìbéèrè Èwo Ni Ìdáhùn
- A máa ń rí gbólóhùn ‘ ìpàdé wa bí oyin” nínú àròkọ. (a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
- irú àròkọ wo ni “Ayẹyẹ ìgbéyàwó tó ṣojú mi láìpẹ́ yìí.
(a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn - Ohun tí ó ṣe pàtàkì fún ẹni tí ó fẹ́ kọ àròkọ láti ṣe ni (a) mímọ èdè é lò (b) kíkọ àròkọ tó gùn (d) ṣíṣe ìlapa èrò. (e) ṣíṣe àtúnkà àròkọ rẹ̀
- Wọ́n kun ara rẹ̀ ní àwọ̀ ewé, bá ni oríṣìíríṣìí iná tí wọ́n fi ṣe ibẹ̀ lọ́sọ̀ọ́ kọjá sísọ jẹ gbólóhùn tí a lè rí nínú àròkọ (a) alápèjúwe. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
- Ohun tí kì í ṣaábà wáyé nínú lẹ́tà kíkọ ní (a) àkànlò èdè (b) àlàyé (d) òwe. (e) ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì
- Kí aláròkọ tó máa kọ àròkọ rẹ̀, ó wúlò kí ó ṣe (a)àròjinlẹ̀. (b) ìfáàrà (d) àmúlò èdè. ( e) àkọtọ́
- Èwo ni kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan ní ìlànà àkọtọ́ ( a) òun (b) jẹ́kí (d) jọ̀wọ́ (e) rántí
- Owó kò níran jẹ́ orí àròkọ
(a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn - Lẹta gbẹ̀fẹ́ ni lẹta sí (a) àlejò (b) ọ̀gá (d) ará (e) ọkùnrin
- ‘ọ̀gá mi ọ̀wọ́n’ jẹyọ nínú àròkọ(a) alálàyé. (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
- ‘ Bàbá mi tòótọ’ nínú àròkọ onílẹ́tà jẹ́ (a) àdírẹ́sì (b) ìkíni (d) ìparí (é) orí ọ̀rọ̀
- Nínú lẹ́tà àìgbagbẹ̀fẹ́, ìgbésẹ tó máa ń tẹ̀lẹ́ àdírẹ́sì ni (a) ìkíni ìbẹ̀rẹ̀ (b) ìkíni ìparí. (d) orí ọ̀rọ̀ (e) ìpín afọ̀
- Ikú jẹ́ àròkọ(a) ajẹmọ ìṣípayá (b) alárìíyànjiyàn. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn
- Ìkòkò tí yóò jẹ ata ìdí tí á ko gbóná jẹ́ àròkọ
(a) alálàyé. (b) onísọ̀rọ̀ngbèsì. (d) onílẹ́tà (e) oníròyìn - Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a)ẹ̀nyin. (b) ẹ̀yin. (d) aiye (e)nwọn
- Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a) òshogbo (b) ṣhàgámù (d) ọlọ́pàá (e) ọffa
- Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a) enia. (b) õrùn (d) ẹiyẹ (e)jẹ́ kí
- Èwo ni àkọtọ́ rẹ̀ bóde mu? (a) gẹ́gẹ́ bí. (b) nígbàtí (d) nítorínaa (e)nlọ
- “Màmá rẹ tòótọ’ nínú àròkọ onílẹ́tà lè jẹ́ a) àdírẹ́sì (b) ìkíni (d) ìparí (é) orí ọ̀rọ̀
- ‘Gbọ̀ngàn ìlú mi’ jẹmọ́ àròkọ (a) aṣàpèjúwe (b)asòtàn. (d) aṣàríyànjiyàn (e)ìsọ̀rọ̀ǹgbèsì
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kejìlá
Déètì: 06/08/2020
Àkòrí: Àpólà orúkọ
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kọkànlá
Fàlà sí ìdí àwọn àpólà-orúkọ inú gbólóhùn wọ̀nyí:
- Ojú Olú wà ní ara mi.
- Àgbò tí a rí ní ọjà wù Ṣọlá.
- Àwọn ọmọdé méjì ń ta ayò.
- Èmí gan an wa lodo ìyá wọn.
- Ó ti pa Adìẹ funfun .
- Mo jẹ́ ọmọ rere.
- Aṣọ pupa ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rí rà ní ọjà.
- Àga tí mo ṣẹṣẹ kàn wà lọ́dọ̀ bàbá àgbẹ̀dẹ.
- Wọ́n ti mo sí ọ̀rọ̀ yìí.
- Ẹ̀yin wọ̀nyí wà níbẹ
Ẹ̀yán
- Olú = èyán ajórúkọ
mi = ẹ̀yán arọ́pọ̀ orúkọ - tí a rí ní ọjà. = ẹ̀yán aláwẹ́ gbólóhùn.
- Ọmọdé /méjì= ẹ̀yán ajórúkọ/aṣònkà
- gan an = ẹ̀yán aṣàfihàn
Wọn = ẹ̀yán arọ́pọ̀ orúkọ - funfun = ẹ̀yán aṣàpèjúwe
- rere = ẹ̀yán aṣàpèjúwe
- pupa = ẹ̀yán aṣàpèjúwe
rẹ̀ = ẹ̀yán arọ́pò orúkọ - tí mo ṣẹṣẹ kàn= ẹ̀yán aláwẹ́ gbólóhùn . àgbède= ẹ̀yán ajórúkọ
- yìí = ẹ̀yán aṣàfihàn
- wọnyìí = ẹ̀yán aṣàfihàn
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kejìlá
Déètì: 06/07/2020
Ṣàlàyé ṣókí lórí nǹkan wọnyìí
- Àáró
- owó èlè
- Ilemoṣu
- Ìsingbà
Isé ọ̀sẹ̀ kọkànlá
30/07/2020
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹwàá
- E –asọrégèé
- D — àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
- É – àsọrégèé
- B – àdàpè
- E- àfiwé tààrà
- A – ọfò
- B — àwítúnwí
- A — Àkànlò Èdè
- É — ìkíni
10.. A — Àkànlò Èdè - 11. B— oríkì
- 12. D — ọfọ̀
- 13. B — àfiwé
- 14. B — àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
- 15. A — àlọ́ àpamọ̀
- 16. E – àsọrégèé
- 17. D – Àkànlò Èdè
- 18. A – ọfọ̀
- 19. B – Ìpolówó ọjà
- 20.D – ọ̀rọ̀ akọ́nilénu
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kọkànlá
Déètì: 30/07/2020
Àkòrí: Àpólà orúkọ
(A) Fàlà sí ìdí àwọn àpólà-orúkọ inú gbólóhùn wọ̀nyí:
- Ojú Olú wà ní ara mi.
- Àgbò tí a rí ní ọjà wù Ṣọlá.
- Àwọn ọmọdé méjì ń ta ayò.
- Èmí gan an wa lodo ìyá wọn.
- Ó ti pa Adìẹ funfun .
- Mo jẹ́ ọmọ rere.
- Aṣọ pupa ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rí rà ní ọjà.
- Àga tí mo ṣẹṣẹ kàn wà lọ́dọ̀ bàbá àgbẹ̀dẹ.
- Wọ́n ti mo sí ọ̀rọ̀ yìí.
- Ẹ̀yin wọ̀nyí wà níbẹ̀.
(B) Ko eyan inu gbolohun yii jade ki o si so iru eyan ti o je .
(B) Kọ àwọn ẹ̀yán inú gbólóhùn òkè yìí jáde kí ó sì sọ irú èyán tí wọ́n jẹ́.
Ise ọsẹ kẹwàá
23/07/2020
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kesàn an
ASA ILE YORUBA
- Ode Asode
Awon ode alagbara ni o maa n saba sode. Won wa fun aabo ilu. Ojuse won ni lati ri i pe ole o ja laarin ilu. Won kii gba owo ise won bi tode oni subgon ilu maa n toju won. Abose ni won maa n fi i se. Oru ni won maa n se ise won. Won maa n ni ohun amusagbara, won a si maa pin ilu si adugbo-adugbo lati maa so. Bi ogun ba de, awon ni won maa ko ara won jo lati lo ja fun ilu.
Ode Adedo
Ọdẹ adẹdò ni awọn ọdẹ ti wọ́n máa pa ẹja ní odò. Àwọn ni apẹja.Ìwọ̀, ìgèrè,àwọn ni wọn fi ń pa ẹja. - Oruko Amutorunwa:-Taiwo – Kehinde –Ige – Ojo – Oke
Oruko Abiku:-Malomo – Ayedun – Kosoko – Kasimaawoo – Durojaye
Oruko Abiso:-Olusoji – Oludare – Olatunde – Adedeji , Adeṣọla – Motanbaje
3. Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ní ayé àtijọ́
- Lílo Ẹ̀yà Ara Fún Ìbánisọ̀rọ̀
(i) Ojú: bí àpẹẹrẹ,a lè fi ojú fa ni mọ́ra, kìlọ̀ fún ènìyàn bẹ́ẹ̀ a lè fi nà ènìyàn. Tí a bá mọ́ ènìyàn lójú ìtumò rẹ̀ ni pé a kò gba tiẹ. Tí a bá ṣẹ́ ojú ìtumò ní pé kí ó dákẹ́.
(ii) Orí: tí a bá mi orí ìtumò rẹ̀ le jẹ́ bẹ́ẹ̀ni,bẹ́ẹ̀kọ́,ó dára tàbí kò dára. O sì tún lè jẹ́ àmì ìkáànú tàbí ìlòdì sí nǹkan.
(iii) imú: tí a bá yímú,a ń fí ẹni náà ṣẹ̀fẹ̀.
(iv) Ẹnu: ti a bá yọ sùtì tàbí yẹ̀gẹ̀ ẹnu sí ènìyàn,a ǹ fí ẹni náà ṣẹ̀fẹ̀. A lè fi ẹnu súfèé.
(v) Èjìká: bí a bá ń báni sọ̀rọ̀ tí a fún tàbí sọ èjìlá ,mo gba ọ̀rọ̀ náà wọlé tàbí mo lòdì sí í.
(vi) Ẹṣẹ̀: bí a bá fi ẹ̀ṣẹ janlẹ̀, àmì ìlòdì sí nǹkan, títẹ ènìyàn mọ́lẹ̀, à ń kìlọ̀ fún un pé kí ó máa ṣe nǹkan tàbí kí ó dákẹ́.
(vii) Èèkánná: ṣíṣẹ́ ni léèkánná túmọ̀ sí ìbáwí, ìkìlọ tàbí àkíyèsí.
(viii) Ọwọ́: bí a bá ṣẹ́ owó sí ènìyàn,a ní kí ó wá tàbí dúró. Tí a bá juwọ́, à ń kí ni tàbí dágbéré. Tí a bá ya owó sí ènìyàn, à ń bú ìyá ẹni náà. - ÌPÀROKÒ
Àrokò jẹ́ ọ̀nà kan tí à ń gbà bá ara ẹni ṣe ní ayé àtijọ́. Bí àwọn àgbà bá fẹ́ sọ̀rọ̀ àṣírí tí ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ ọ́ fún kò sí nítòsí, tàbí tí wọ́n bá fẹ́ ránṣẹ́ sílẹ̀ ní àṣírí, àrokò ni wọ́n ń lò.
Àwọn ọ̀nà tí àwọn baba-ńlá wa ń gbà pàrokò ránṣẹ sí ènìyàn nì wọ̀nyí:
(i) Ìlù lílù: ìlù ni àwọn baba-ńlá wa fí máa ń ránṣẹ sí ojú ogun. Wọ́n máa ń lù ìlù láti fi túfọ̀ òkú àgbàlagbà.
(ii) Ọ̀pá Àṣẹ: ọba nìkan ni ó ń fi ọ̀pá àṣẹ pàrokò. Ọba máa ń fi ọ̀pá àṣẹ ránṣẹ́ láti fi hàn wí pé òun wà níbẹ̀. Bí ọba bá sí fẹ́ rí ẹnìkan ní kíákíá ọ̀pá àṣẹ ni yóò fi ránṣẹ́ sí í.
(iii) Owó Ẹyọ: Àwọn babaláwo àti olóriṣà-oko ni wọ́n ń fi owó ẹyọ pàrokò. Ìpè pàjàwìrì lórí kí a fi ojú kan ni ni èyí máa ń túmọ̀ sí.
(iv) Ìyẹ́ Adìẹ: tí a bá tu ìyẹ́ adìẹ fún ọkùnrin kan, ìkìlọ ni pé kí ó jáwọ nínú níní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú obìnrin.
(v) Owó Ẹyọ meta: tí a bá dì í ránṣẹ́ sí ẹni kan, ìtumọ̀ ẹ̀ ni pé ẹni náà ti di ẹni ìtanù.
(vi) Ìgbàlẹ̀: tí a bá fi ìgbálẹ̀ ránṣẹ sí ènìyàn, ẹni tí ó pàrokò ránṣẹ yìí kò fẹ́ rí ẹni tí ó pàrokò náà ránṣẹ́ sí mọ́ nínú ilé rẹ̀.
(vii) Èèpo igi àti aṣọ pupa: tí a bá fi nǹkan yìí ránṣẹ́ sí ọkùnrin tó wà ní ìdálẹ̀, ó túmọ̀ sí pé oyún tí ó fi sílẹ̀ ní ilé tí bàjẹ́.
- 3 Àalè pípa:tí wọ́n bá bá ààlè lé igi eléso kan, ìkìlọ̀ nìyí pé a kò gbọdọ̀ ká èṣo náà.
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹwàá
Déètì: 23/07/2020
Àkòrí: Ọ̀nà Èdè ( ọgbọ́n ìtọpinpin)
Irú ọ̀nà èdè wo ni ó wà nínú àwọn ìpèdè yìí:
- Ìbá ṣe pé ọ̀run ò jìnà,ǹ bá lọ láàárọ̀, ma dé lọ́jọ́ alẹ́. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àsọrẹ̀gèé
- Ẹlẹdẹ ni TỌ́lání. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
- Tíṣá gbá ọmọ létí, etí re sì fàya (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àsọrégèé
- Mo fẹ́ lọ dáwà tilẹ. (a) Àkànlò Èdè. (b) àdàpè (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àsọrégèé
- Ètè rẹ fẹ́lẹ́ bí ọ̀bẹ ìrẹ́lẹ́(a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
- Omi kìí sàn kó bójú wẹ̀yìn. (a) ọfọ̀. (b) Àkànlò Èdè. (d) àwítúnwí. (e) ìkíni
- Mo wí wí wí, o fàáké kọ́rí. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
- Fàáké kọ́rí.(a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
- Ojú gbooro ooo.. (a) ọfọ̀. (b) Àkànlò Èdè. (d) àwítúnwí. (e) ìkíni
- Fi ọwọ́ fa jọ̀gọ̀dì. (a) Àkànlò Èdè. (b) àwítúnwí (d) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (e) àfiwé tààrà
- Wínní wínní lójú orogún. (a) àlọ́ àpamọ. (b) oríkì. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
- A díá fún máa jẹyọ nínú a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
- Ó dúdú bí kóró isin (a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
- Ọ̀bọ ni Ṣọlá. a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
- Ọ̀pá tín-ín-rín kanlẹ̀ ó kànrun. (a) àlọ́ àpamọ. (b) àfiwé. (d) ọfọ̀. (e)ẹsè ifá
- Ayé gbó ọ̀run mọ̀.(a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé
17.Ẹja n bákàn. (a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé
- Igba eṣinṣin kì í dènà dowó. (a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé
- Láńgbé orí ebè jẹ́. (a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) Àkànlò Èdè. (é) àsọ̀régèé
- Ọ̀bọ ń gbọ́bọ gọ̀pẹ jẹ́
(a) ọfọ̀ (b) ìpolówó ọjà. (d) ọ̀rọ̀ akọ́nilẹ́nu (é) àsọ̀régèé
16/07/2020
Ose kesan
Atunse si ibeere ise ose kejo
Kọ ọ̀rọ̀ ìṣe inú gbólóhùn ọkan sílẹ, kí ó sì sọ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́
- pọ́n = oro ise alaigbabo/ asapejuwe
- pa = oro-ise agbabo
- fa ya = oro-ise elela
- gbe, pon, gun = oro ise asinpo
- jókòó = oro-ise akanmoruko
- ..kú .. kú = oro ise alapepada
- jọ̀wọ́ = oro ise apase
- bí = oro -ise asoluwadabo
- dà? = oro-ise asebeere
- ga. = oro-ise asapejuwe
Ise ose kesan-an
Deeti : 16/07/2020
Akori: Asa ile Yoruba
- salaye soki lori ode adedo ati ode asode
- ko apeere marun -un marun-un fun okookan isori oruko Yoruba wonyi: (a) oruko amutorunwa
(b)oruko abiku
(d) oruko abiso
3. salaye ona ibanisoro aye atijo meta
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kejo
Déètì:09/07/2020
Atunse si ibeere ise ose keje
SILEBU
- Orisii batani meta ni o wa: i]lilo kiki faweli gege bi silebu [F]
ii] lilo konsonanti ati faweli gege bi silebu [KF]
iii] lilo kononanti aranmupe asesilebu gege bi silebu [N ) - [F]: e wa, o lo, a n bo
(KF): wa, lo, gba, sun
(N): n lo, n bo, n ke, o/ro/m/bo, pa/n/la
3
i. gongosu- go/n/go/su – KF-N-KF-KF
ii. igbale- i/gba/le – F-KF-KF
iii. panpe- pa/n/pe – KF-N-KF
iv. ologbon- o/lo/gbon – F-KF-KF
v. jagunjagun-ja/gun/ja/gun – KF-KF-KF-KF
vi. kindinrin- kin/din/rin – KF-KF-KF
vii. maa- ma/a – KF-F
viii. nla- n/la – N-KF
ix. orombo- o/ro/m/bo – F-KF-N-KF
x. sun- sun – KF
Àkíyèsí (N) ló máa dúró fún kọ́ńsónáǹtì aránmú asesílébù.
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹjọ
Déètì: 09/07/2020
Àkòrí: ọ̀rọ̀ ìṣe
Kọ ọ̀rọ̀ ìṣe inú gbólóhùn ọkan sílẹ, kí ó sì sọ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́
- Èso náà pọ́n.
- Ìyá pa ẹja.
- Ṣọlá fa ìwé mi ya.
- Titi gbé ọmọ pọ̀n gun orí igi.
- Ṣọlá jókòó sílẹ.
- Ó’ kú alàgbà náà kú kan.
- Ẹ jọ̀wọ́.
- Inú bí Òjó.
- Ìwọ dà?
- Ọmọ náà ga.
02/07/2020
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹfà
Awẹ́ gbólóhùn afarahẹ́ | orísìí awé gbólóhùn afarahẹ́ |
1. tí ó jẹ mí | aṣàpèjúwe |
2. Bí ọ bá fẹ́ | aṣapọ́nlé |
3. pé Adé wá | Asọdorúkọ |
4. kàkà kí ń jalè | aṣàpọ́nlé |
5. tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ | aṣàpèjúwe |
6.tí Adé ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ | aṣàpèjúwe |
7.tí ó sùn | aṣàpèjúwe |
8. pé ọmọ náà wà láàyè | asọdorúkọ |
9.tí mo rà | aṣàpèjúwe |
10. nígbà tí ọkọ̀ kọ lù ú | aṣàpọ́nlé |
Isé ṣiṣẹ́ fún ọ́sẹ̀ keje
Déètì:02/07/2020
Àkòrí:Sílébù
- Oríṣìí bátánì Sílébù mélòó ni ó wà nínú èdè Yorùbá? Dárúkọ wọn.
- Kọ àpẹẹrẹ ọrọ kan ṣoṣo tí ó fi àwọn bátánì Sílébù náà hàn.
- Pín ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Sílébù kí o sì kọ ìhun wọn jáde
(i) gọ̀ǹgọ̀sú
(ii) ìgbálẹ̀
(iii) páńpẹ́
(iv) ọlọ́gbọ́n
(v) jagunjagun
(vi) kíndìnrín
(vii) maa
(viii) ńlá
(ix) òroḿbó
(x) sùn
25/06/2020
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún
- Ṣàlàyé ohun tí ìrèmọ̀je jẹ́
- Ọgbọn ẹ̀wẹ́ wo ni ìjàpá lò nínú àlọ́’Erin fẹ́ jọba’?
- Báwo ni Òbísẹ̀san àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe bọ́ lọ́wọ́ àwọn gbọ́mọgbọ́mọ?(ìgbìn laláyò ń ta)
4.kín ni àlá tí ìyá Ṣọlá lá sí ọmọ rẹ̀ Ṣọlá?(ọ̀rẹ́ mi)
Iremoje je orin aro tàbí ewi alohun ti egbe ode maa n ko lati se oro isipa ode ti o ba ti ku nile Yoruba. Ogun lo ni orin Iremoje. Orin ti o ni agbara bii ofo ni, kii se ohun ti enikan le ranti tan. A kii ko losan afi ni oru. Tokunrin, tobinrin ni o n sun Iremoje sugbonawon okunrin lo poju ti o n sun. Idije ni awon egbe ode maa n fi Iremoje sisun se, won a si maa gbeye lowo ara won. Oriki ode to ku a maa je yo ninu Iremoje. Kiko ni won ko Iremoje, kii se amutorunwa. Awon to mo sun daadaa ni I saaju orin Iremoje ti awon egbe omo ekose naa yoo si maa gbe e. Ìlù àgbẹ tí ṣe ìlù ògún ní wọn máa ń lù sí í.
2.
Ni ilu kan laye atijo, awon ara ilu naa fe difa eni ti yoo je Oba won. Bi awon ara ilu se dia ni Ifa so pe won gbodo fi Erin se etutu ki o to di wipe won fi omoye ti Ifa mu gege bi Oba. Ibeere ti o wa lenu gbogbo ara ilu nipe nibo ni awon yoo ti ri Erin lati fi se etutu. Yato sipe Erin je eranko nla ti eniyan ko le fi owo kekere mu, Erin soro so mole a wugi lo. Ibanuje ni gbogbo ara ilu wa nitori won ko mo bi won se maa ri Erin setutu. Ijapa da awon ara ilu loju pe oun yoo mu Erin wa laaye. Opolopo awon eniyan ni o fi Ijapa se yeye pe se pelu bi o se kere to ni o fe lo mu Erin nla kan wa. Nigbeyin, won je ki Ijapa pa itu owo re. Ijapa ologbon ewe din akara ti o fi oyin si, o gba inu igbo lo. Nigba to de be, o bere si ni pon Erin nile pe oun ni Oba gbogbo awon eranko. Inu Erin dun si eyi, Ijapa tun fun ni akara oloyin je. Ijapa so fun Erin pea won omo adarihunrun fe fi je Oba. Erin ko gba nkan ti Ijapa so gbo, o bere sin i rerin. Ijapa tun fun Erin ni akara oloyin je, bayi ni Erin dahun pe oun yoo lo. Inu Ijapa dun, o gun ori Erin, irin bere. Lona, Erin fe pada, Ijapa tun fun ni akara oloyin je, won tun bere sii maa lo. Ki won to de igboro, Ijapa ti so fun awon eniyan pe ki won gbe koto jinrawo kan, ki won te aso aran le, ki won si gbe aga Oba le. Bi Ijapa se yo pelu Erin, inu gbogbo won dun, won si bere sin i korin. Bayii ni Ijapa so fun Erin pe ki o jokoo si ori aga Oba ti won ti pese fun. Bayii ni Erin jokole aga naa,ti o si ja sinu koto ni yen. Awon ode yo,won si ta Erin ni ibon titi o fi ku. Bayii ni Ijapa se lo ogbon ewe fi Erin se etutu.
3.
Obi ati egbon re wa ise lo si ilu Ibadan. Won sa gbogbo ipa won, pabo lo bo si. Ore egbon won ti won fi oro ise wiwa won to leti ni ki won pade oun ni afeemojumo ni eba ile iwosan Adeoyo. Won se bee, sugbon won ko mo pe ile ko I ti mo pupo ti won fi gbera lo pade re. Won bo si owo awon gbomogbomo. Won di Obi ati egbon re si igbo kan nitosi. Obi ati egbon re wa nibe, won wa ona abayo si okun ti awon gbomogbomo fi de won. Ninu akitiyan ati bo ninu ide yii, won ri koto kan, eyi ti o gba eniyan ni iduro. Won ko si nu koto naa. Nigba ti awon agbenipa de, won si ilekun, won ko ri won mo. Won fija peeta laarin ara won, oro di bo-o-lo-o-ya-fun-mi. won ja titi,won tuka won si gbagbe ati tikeun. Leyin ti won lo tan, Obi ati egbon re bo si ta won si farapamo ki ile ko mo. Nigba ti ile mo, won gba ile won lo. Bayii ni won bo lowo awon gbomogbomo.
4
Àlá tí ìyá Ṣọlá lá sí ọmọ rẹ̀ Ṣọlá
Ìyá Ṣọlá lá àlá rí bàbá tí Irun rẹ̀ funfun báláú, tí ó sì wọṣọ funfun. Bàbá náà pé Ṣọlá, ó sì gbé oúnjẹ àdídùn kan lé e lọ́wọ́ tẹ̀ríntẹ̀rín. Ṣọlá gbé oúnjẹ lọ ṣe àwọn òbí rẹ̀. Inú gbogbo wọn dùn nítorí pé ẹbí ti pa wọ́n. Oúnjẹ náà dùn débi pé gbogbo ènìyàn ló ń gbóòórùn títa sánsán rẹ̀.Afẹ́fẹ́ kan bẹ sí ní fẹ́ sí Ṣọlá àti oúnjẹ. Lójijì ni afẹ́fẹ́ náà di ìjì líle tí ó sì gba oúnjẹ náà lọ́wọ́ Ṣọlá . Ṣọlá bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún, àwọn òbí rẹ̀ naa ń sunkún ṣugbọn wọn kò le rán án lọ́wọ́.
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ Kẹfà
Déètì:25/06/2020
Fa àwọn awé gbólóhùn farah tí ó wà nínú gbólóhùn yìí kí ó sì sọ oríṣìí awé gbólóhùn tí ó jẹ́
- Màá gbowó tí ó jẹ mí .
- Bí ọ bá fẹ́ ọ lè pè mí.
- Ó yà mí lẹ́nu pé Adé wá.
- Kàkà kí n jalè ma kúkú dẹrú.
- Fẹmi tí à ń se rẹ̀ ti dé.
- Ọkùnrin kúkúrú tí Adé ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti kú.
- Àpínké tí ó sùn ti dìde.
- Ó dá mi lójú pé ọmọ náà wà láàyè.
- Aṣọ funfun tí mo rà dára.
- Ajá náà kú nígbà tí ọkọ̀ kọ lù ú.
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún
18/06/2020
Mo kí Olugboji Fèyíkẹ́mi kú u iṣẹ́. Ó ń ṣe dáradára. Mo ń fi àsìkò yìí rọ ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ mi tókù kí ẹ̀yin náà kópa nínú
Ìdáhùn sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹrin
- Pín àwọn ọ̀rọ̀ àyálò yìí sí àfétíyá àti àfojúyá : tébù, Pétérù, tíṣà, bọ́tà, Díákónì, ráìsì, télọ̀, párádísè, pẹ́nsù, Ẹsítérì.
̀ọ̀rọ̀ àyálò àfétíyá
tébù
tíṣà.
bọ́tà
télọ̀
pẹ́nṣù
ráìsì
Ọ̀rọ̀ àyálò àfojúyá
Pétérù
Párádísè
Díákónì
Ẹsítérì - Kọ bí a ṣe lè yá àwon ọ̀rọ̀ gẹ̀ẹ́sì yìí wọ inú èdè Yorùbá : fork, tailor, brick, globe, ink, razor,driver, hospital,minister, messenger.
ork = fọ́ọ̀kì/fọ́ọ̀kù
tailor – télọ̀
brick – bíríkì
globe – gílóòbù
ink. – yín-ìnkì
razor – réṣọ̀
driver – dírẹ́bà/dírẹ́fà/dẹ́rẹ́bà
hospital – ọsibítù/ọsipítū
minister – mínísítà
messenger – mẹ́séńjà
3a. Kín ní ìpàrójẹ/ìpajẹ? Ìpajẹ ni fifó àwọn ìró nígbà tí a bá n ṣafọ̀ geere.ìró tí a pajẹ lè jẹ́ ìró kọ́ńsónáǹtì, fáwẹ́lì àti ohùn .
b. Fi àpẹẹrẹ méjì méjì hàn fún ìpajẹ kọnsónáńtì àti ìpajẹ fáwẹ̀lí
Ìpajẹ kọ́ńsónaǹtì b.a
gbárìyẹ̀ – gbárìẹ̀ (y)
Ọ̀mọlúàbí – ọmọlúábí (w)
Kẹ́hìndé – kẹ́ìndé (h)
Èkùrọ́ – èkùọ́ (r)
Ìpajẹ fáwẹ̀lì
ra ilé – ralé (i)
etí odò – etídò (o)
ra aṣọ – raṣọ (a)
Ifákúnlé – fákúnlé(I)
Adéjọbí – Déjọbí (A)
d. Tọka sí àwọn ìró tí a pajẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí:
àkàà ìró (r) àkàrà
èkùọ́, ìró (r) èkùrọ́
dáa ìró (r) dára
gbárìẹ́ ìró (y) gbáìyé
gboùngboùn ìró (h) gbohùn gbohùn
,ọmọlúàbí ìró (w) ọmọlúwàbí
ralẹ̀ ìró (I) ra ilé
etídò ìró (o) etí odò
dáràn ìró (ọ̀̀)dá ọ̀ràn
fọṣọ ìró (a) fọ aṣọ
4a. Kín ní àrànmọ́? Àrànmọ́ ni kí ìró kan ní agbára lórí ìró Kejì láti sọ ìró Kejì di bi ara tirẹ̀.
b. Ṣàlàyé oríṣìíríṣìí àrànmọ́ méjì pẹ̀lú àpẹẹrẹ mẹ́ta mẹ́ta.
Àrànmọ́wájú: tí fáwẹ̀lì àkọ́kọ́ bá rán mọ́ èkejì.
ará ilé – aráalé
owo iṣẹ́ – owó iṣẹ́
àpò iyọ̀ – àpòoyọ̀
Àrànmẹ́yìn : tí fáwẹ̀lì èkejì bá ràn mọ́ ti àkọ́kọ́.
ará oko – aráako
Ìyá ẹgbẹ́ – ìyẹ́ẹgbẹ́
Ọmọ ọkọ – ọmooko
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ karùn ún
Déètì: 18/06/2020
Àkòrí: Lítíréṣọ̀ Yorùbá
Dáhùn ìbéèrè yií
- Ṣàlàyé ohun tí ìrèmọ̀je jẹ́
- Ọgbọn ẹ̀wẹ́ wo ni ìjàpá lò nínú àlọ́’Erin fẹ́ jọba’?
- Báwo ni Òbísẹ̀san àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe bọ́ lọ́wọ́ àwọn gbọ́mọgbọ́mọ?(ìgbìn laláyò ń ta)
4.kín ni àlá tí ìyá Ṣọlá lá sí ọmọ rẹ̀ Ṣọlá?(ọ̀rẹ́ mi)
11/06/2020
Ẹ kú u deédé àsìkò yìí o ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ mi,mo kí yín kú u iṣẹ́.
Àtúnṣe sí ìbéèrè iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹta
1a. O GBA FOLA LETI
b. BIMPE TI FUN UN
d. BABA YIN TI DE ILE WA LONI
e. SOJI TI FUN WON
e. A SARE KOJA ILE TOPE
2a. Wọ́n= Ẹnìkẹta ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà
I = Ẹnìkẹta eyo ni ipò àbọ̀
b. Ẹ = Ẹnìkejì ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà
mí = Enikìíní ẹyọ ní ipò àbọ̀
d. yín =Ẹnìkejì ọ̀pọ̀ ní ipò ẹ̀yán
rẹ̀ = Ẹnìkẹta ẹyọ ní ipò ẹ̀yán
e. Mo =Ẹnikìíní ẹyọ ní ipò olùwà
wọn = Ẹnìkẹta ọ̀pọ̀ ní ipò ẹ̀yán
e. Ó. = Ẹnìkẹta ẹyọ ní ipò olùwà
wa. =Ẹnikìíní ọ̀pọ̀ ní ipò àbọ̀
Déètì: 11/06/2020
Àkòrí: Ètò Ìró
Dáhùn ìbéèrè wọ̀nyìí lórí ọ̀rọ̀ àyálò, ìpàrójẹ àti àrànmọ́
- Pín àwọn ọ̀rọ̀ àyálò yìí sí àfétíyá àti àfojúyá : tébù, Pétérù, tíṣà, bọ́tà, Díákónì, ráìsì, télọ̀, párádísè, pẹ́nsù, Ẹsítérì.
- Kọ bí a ṣe lè yá àwon ọ̀rọ̀ gẹ̀ẹ́sì yìí wọ inú èdè Yorùbá : fork, tailor, brick, globe, ink, razor,driver, hospital,minister, messenger.
3a. Kín ní ìpàrójẹ/ìpajẹ?
b. Fi àpẹẹrẹ méjì méjì hàn fún ìpajẹ kọnsónáńtì àti ìpajẹ fáwẹ̀lí
d. Tọka sí àwọn ìró tí a pajẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí: àkàà, èkùọ́, dáa, gbárìẹ́, gboùngboùn,ọmọlúàbí, ralẹ̀, etídò, dáràn,fọṣọ
4a. Kín ní àrànmọ́?
b. Ṣàlàyé oríṣìíríṣìí àrànmọ́ méjì pẹ̀lú àpẹẹrẹ mẹ́ta mẹ́ta.
Ọ̀sẹ̀ Kẹta
Déètì: 04/06/2020
Ìdáhùn sí ìbéèrè ọ̀sẹ̀ Kejì
- A – àkọsẹ̀jayé
- E – àgbẹ̀
- E – babaláwo
- E – odó gbígbẹ́
- A- alágbède
- A – ahunṣo
7 B – àredú o - Ọ̀lẹ
- A- àgbẹ̀
- A- àjọ
- A – san ẹ̀bẹ̀sẹ́ padà
- E- orí dífá
- B- dàndógó
- A- gbérí ọdẹ
- A- abìdán
- A- fìlà
- B- olóólà
- E- Òndó
- D- ìkòrì
- E- ẹ̀kẹ́
- B – ayò
- D – ọ̀yàyà
Iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kẹta 04/06/2020
Àkòrí: Ọ̀RỌ̀ ARỌ́PÒ ORÚKỌ
Dáhùn ìbéèrè yií
- Kọ gbólóhùn tí yóò fi ìrísí àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò ọrúkọ wọ̀nyìí hàn. Rí i pé o fa ìlà sí abẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò ọrúkọ náà.
(a) ẹnìkejì ẹyọ ní ipò olùwà
(b) ẹnìkẹta ẹyọ ní ipò àbọ̀
(d) ẹnìkejì ọ̀pọ̀ ní ipò ẹ̀yán
(e) ẹnìkẹta ọ̀pọ̀ ní ipò àbọ̀
(ẹ) enikìíní ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà - Tọ́ka sí ọ̀rọ̀ arọ́pò ọrúkọ nínú gbólóhùn yìí,kí ọ sì ṣe àpèjúwe (ẹni,iye àti ipò) ìkọ̀ọ̀kan wọn
(a) wọ́n rán sí í.
(b) Ẹ gbọ́dọ̀ rán mi lọ.
(d) Iṣẹ́ yín ti parí lọ́dọ̀ rẹ̀.
(e) Mo n fọ abọ́ wọn.
(ẹ) Ó sáré tẹ̀lé wa.
(Bí o bá ní ohun kan tí ó rú ọ lójú tàbí ìbéèrè lórí isé kan,kọ ọ sí ìsàlẹ̀ ìdáhùn rẹ.)
IRE OO!
Deeti:28/05/2020
Ose keji
Idahun si awon ibeere ise ose kiini
- Mofiimu ni ege ti o kere julo ti o si ni itumo ninu girama ede Yoruba.
- (i) Mofiimu afarahe: eyi ni mofiimu ti ko le da duro funra re laije pe a kan oro miiran mo on.Apeere:oni, ai, ati, a, e, I, o, abbl
(ii) Mofiimu adaduro/ipile: eyi ni mofiimu ti o le da duro ti yoo si ni itumo.Apeere: ile, aga, awa, jokoo, gba, obe abbl - (i) a+ko+ope
(ii) omo+obinrin
(iii) olu+ko
(iv) wo+ile+wo+ile
(v) oni+akara
(vi) ti+eyin
(vii) iran+de+iran
(ix) ai+ni+owo+ni+owo
(x) I+gba+ile
Ise ose keji
Deeti:28/05/2020
Akori: Asa ile Yoruba
Ibeere Ewo ni Idahun Lori Asa Yoruba
- Asa ti a fi n mo ise ti omo yoo se ni _(a)akosejaye. (b) ikomojade (d)ifa dida (e) iwure
- Ise akoko ti awon baba nla wa koko se ni ise __.(a)aso hihun (b) ila kiko (d)ilu lilu (e) agbe
- Aboruboye ooo ni a ki_____. (a)alaro (b)aborisa (d)ode (e)babalawo
- Ise ona ni __.(a)aso hihun (b)epo fifo (d) ode sise (e) odo gbigbe
- Emu je ara ohun elo ise _. (a)alagbede (b)ode (d)gbenagbena (e)ahunso
- Biribiri je ara ohun elo ise __.(a) ahunso (b)alagbede (d)ode (e)agbe
- Alaro ni a n ki ni __. (a) arepa o. (b) aredu o (d)aroye o (e) arinpa o
- Eni kan to Yoruba gba pe ko se e ba se ise ajumose ni _.
- Eni ti aaro sise pe fun ju ni __. (a) agbe (b)onidiri (d)aso hihun (d)ode. (e)agbede
- Iye ti a ba da ni a n ko ki i se oro _.(a)ajo (b)aaro (d)eesu (e)ebese
- Iyato laarin ebese ati owe ni pe a ki I (a) San ebese pade (b) San owe pada (d)fi eesu San an pada (e) fi ajo San an pada
- Ewo ni o jemo oge sise okunrin? (a) eyin pipa (b) irun Didi (d)laali lile (e) ori fifa
- Aso imurode okunrin ni____. (a)iteko (b)dangodo (d) tobi (e)aran
- Aso ise fun okunrin ni____. (a)gberi ode (b) dansiki (d)kafutaani (e)kijipa
- Orisii sokoto okunrin ni _.(a)abidan (b)kijipa (e)sulia
- Okiribi,adiro,ikori ati onide je apeere __(a)fila (b)sokoto (d)buba (e) irun Didi
- Awon wo ni o n ko ila oju? (a) alagbede (b)oloola. (d) gbenagbena. (e) onise ona
18.ila ooro kookan ni ereke ni ila awin . (a) Egba (b) Ijebu. (d)Ondo (e)Oyo 19.Apeere ila oju kiko ni yii ayafi. (a) keke (b)gombo (d)abaja (e)ikori - Ewo ni ki I se ere osupa ninu ere idaraya wonyii? (a) bojuboju (b)ekun meran (d) bookobooko (e)eke
- Ere pataki ti n lo ogbon inu ni _____. (a) arin tita. (b) ayo tita (d) ijakadi. (e ) bojuboju
- Ona kan pataki to Yoruba fi n mo omoluabi ni nini_____. (a) aso. (b) ewa. (d) oyaya. (e) owo
OSE KIINI
Deeti: 21/05/2020
Akori Eko: Ihun ati Iseda oro (MOFIIMU)
E ku u deede asiko yii eyin akekoo mi, a si ku u ifarada asiko yii, Oluwa a ko wa yo o. (Amin) Mo ro yin ki e lo asiko yii lati fi gbajumo iwe yin , E o se aseyori o.(Amin)
E je ki a dahun ibeere wonyii lori eko ti a ti ko seyin eyi ti se: Ihun ati iseda oro.
- Ki ni Mofiimu?
- Daruko orisii Mofiimu to wa pelu apeere mejimeji.
- Mofiimu meloo lo wa ninu awon oro yii?se afihan ipin si Mofiimu won.
(i) akope
(ii) omobinrin
(iiioluko
(iv) wolewole
(v)alakara
(vi) teyin
(vii)iranderan
(viii) arolayo
(ix) ailowolowo
(x) igbale.
Dahun ibeere re nipa titele ilana isale yii. jowo ri i daju pe o ko oruko ise (Yoruba) sinu akamo isale yii.
No Fields Found.